Courtois: Aṣọ́lé Chelsea fibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí Real Madrid torí £35m

Thibaut Courtois àti Florentino Pérez Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Thibaut Courtois dèrò ikọ̀ Real Madrid

Aṣọle Thibaut Courtois to jẹ ọmọ orilẹ-ede Belgium ti fi Chelsea silẹ lọ Real Madrid fun owo to to £35m

Loni Ọjọbọ ni Courtois to gba ami ẹyẹ aṣọle to pegede julọ ninu idije ife ẹyẹ agbaye Russia 2018 darapọ mọ ikọ Madrid lẹyin t'awọn dokita ṣayẹwo rẹ tan.

Ẹgbẹ agbabọọlu naa ki kaabọ si olu ilu orilẹ-ede Spain loju opo Twitter wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Courtois to jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn bọwọ luwe adehun ọdun mẹfa pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid.

Ọdun mẹfa ni Courtois fi gba bọọlu fun ikọ Chelsea ṣugbọn ẹgbẹ agbabọọlu Atletico Madrid lo ti lo ọdun mẹta akọkọ.

Ẹwẹ, Chelsea rọpo Courtois pẹlu aṣọle Kepa Arrizabalaga lati ikọ Athletic Bilbao, £71.6m ni wọn fi raa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aṣọle tuntun ni ẹgbẹ́ tuntun

Arrizabalaga ti di aṣọle ti owo ti wọn fi ra pọju bayii, aṣọle ti owo ti wọn fi ra pọju ṣikeji ni Alisson Becker ti Liverpool ra ni £66.8m.

Ọjọbọ ni awọn ikọ agbabọọlu nilẹ Gẹẹsi ni anfani mọ lati ra agbabọọlu fun saa yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSMS alert: Wo ọ̀nà láti dẹ́kun jìbìtì lórí àṣùwọ̀n báǹkì rẹ