Eré bọ́ọ̀lù: Musa gbá bọ́ọ̀lù sáwọ̀n fún ikọ̀ tuntun

Ahmed Musa Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ahmed Musa ti bẹ̀rẹ̀ sí máa sanjọ́ fún ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù tuntun rẹ̀

Aaya bẹ silẹ o bẹ sare ni Ahmed Musa fi ṣe lẹyin to saaju ikọ Al Nassr FC to ṣẹsẹ darapọ mọ nibi ti wọn jawe olubori pẹlu ami ayo meji si ẹyọkan lọjọ Aje.

Musa gbayp kan wọle, o ṣi sẹ iranwọ fun ẹlẹẹkeji bi ẹgbẹ agbabọọlu Al Nassr FC ti fagba han AlJazira UAE ninu idije Arab Clubs Champions Cup.

Ifẹsẹwọnsẹ naa ni alakọkọ iru rẹ ti Musa yoo ti kopa lẹyin to darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹ o ranti wipe ti orin tilu ni awọn ololufẹ ikọ Al Nassr FC fi ki Musa kaabọ lẹyin to darapọ mọ wọn.

Ikọ agbabọọlu ilẹ Gẹẹsi Leicester City ni Musa ti darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Al Nassr FC lorilẹede Saudi Arabia