Super Cup: Ààyè Cristiano Ronaldo yọ sílẹ̀ nínú ìdíje

Real Madrid àti Atletico Madrid Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Láti ìlú kan naa ni Real Madrid àti Atletico Madrid ti wá

Gareth Bale kò le gba ikọ Real Madrid lẹyin ti alatako wọn Atletico Madrid fiya jẹ wọn pẹlu ami ayo mẹrin si meji (4-2) ninu idije Super Cup ni Estonia.

Ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ naa ni akọnimọọgba tuntun fun Real Madrid, Julen Lopetegui sọ pe agbabọọlu Bale ni yoo rọpo agbaọjẹ agbabọọlu Cristiano Ronaldo to fikọ naa silẹ lọ si Juventus saaju idije Super Cup.

Sugbọn omi pọ ju ọka lọ lẹyin ti Bale ko tii ri ayo kankan gba sawọn bi o tilẹ je pe o wa lori papa ti wọn fi pari ifẹsẹwọnsẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bawo ni idije naa ṣe lọ?

Ẹlẹsẹ ayo Diego Costa lo kọkọ gba bọọlu sawọn fun Atletico ki Karim Benzema too da ayo naa pada, balogun ikọ Madrid sọ ayo di meji fun Madrid, sugbọn Costa da a pada.

Saul Niguez ati Koke lo jẹ ki Atletico jawe olubori lẹyin ti awọn mejeeji gbayo wọle ni ipele afikun asiko (extra time).

Idije Super Cup maa n waye laarin ikọ to ba gba ife ẹyẹ UEFA Champions League ati Europa League

Ilu Tallinn to jẹ olu ilu orilẹ-ede Estonia ni ifẹsẹwọnsẹ naa ti waye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOgundiya: Àṣìṣe Dókítà ló sọ mi di aláàbọ̀ ara lórí kẹ̀kẹ́