Man Utd, Arsenal pegede, Tottenham fidirẹmi

Aworan Romelu Lukaku

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Goolu meji ni Romelu Lukaku jẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Burnley

Nkan ti n jọ bi ẹni wi pe o n bọ sipo pada fun akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United Jose Mourinho pẹlu bi ikọ rẹ ti se gbowuro soju Burnley.

Ayo meji ti Romelu Lukaku gba wọle lo se atọna iyipada yi.

Ninu ifẹsẹwọnsẹ meji ti wọn gba kẹyin,Man Utd fidirẹmi ni.

Oríṣun àwòrán, LINDSEY PARNABY/AFP/Getty Images

Lati abala ikini ifẹsẹwọnsẹ naa ni Lukaku ti jẹ goolu mejeji sugbọn Marcus Rashford gba kaadi alawọ pupa fun pe o fi ori sọ agbabọọlu Burnley Phil Bardsley.

Manchester United ko ba jẹ goolu mẹta ninu ifẹsẹwọnsẹ naa sugbọn Paul Pogba kuna lati jẹ goolu gbe sile gbasile ti wọn ri.

Alexandre Lacazette satọna aseyọri Arsenal

Adura awọn ọlolufe ẹgbẹ Arsenal gba pẹlu bi wọn ti se ri aseyọri akọkọ fun saa bọọlu ọdun yi ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Cardiff City.

Shkodran Mustai,Pierre Emerik Aubameyang lọw ninu aseyọri yii sugbọn Alexandre Lacazette lo kase eto nilẹ ni isẹju mọ́kànlélọ́gọ́rin ifẹsẹwọnsẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Alexandre Lacazette n yọ pẹlu goolu rẹ to jẹ fun Arsenal ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Cardiff

Ewẹ,Pabo ni akitiyan Kelechi Iheanacho ati Wilfred Ndidi Naijiria ja si pẹlu bi Liverpool ti se fagba han Lecicester City ninu ifẹsẹwonsẹ English Premiership

Ami ayo meji si ookan ni wọn fi ṣagba wọn.

Sadio Mane jẹwọ orukọ rẹ pẹlu bo ti ṣe ṣidẹ goolu alakọkọ ni isẹju kẹwa ifẹsẹwonsẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Goolu elekeji ti Sadio Mane yoo jẹ fun Liverpool re ni saa bọọlu ọdun yi

Roberto Firminho naa ko gbẹyin pẹlu bo ti ṣe gba goolu keji wọle ki abala kini ifẹsẹwonsẹ oun to pari.

Sugbọn asọle Liverpool ṣe bi ẹni da omi ọka lu ina fun wọn nigba ti aṣiṣe rẹ ṣeṣe atọna goolu kan ṣoṣo ti Leicester da pada.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Kelechi Iheanacho ji bọọlu gba lọwọ asole Liverpool to si se atona goolu ti Leicester jẹ

Nigba ti o n fẹsi si aṣiṣe yi lẹyin ifẹsẹwonsẹ wọn, akọnimọgba Liverpool Jurgen Klopp ni ''mo tin fura si wi pe aṣiṣe yoo waye ṣugbọn mi o ro wi pe ninu ifẹsẹwonsẹ yi ni yoo ti ṣẹlẹ''

Pẹlu abajade yi, Liverpool lo n le tente lórí afárá Premiership pẹlú àmì 12.

Hazard ati Pedro fakọyọ fun Chelsea

Eyi ni igba kẹrin ti Chelsea yoo jawe olu bo ri labẹ akọnimoogba wọn tuntun Maurizzio Sarri.

Eden Hazard to je Balogun ikọ naa ṣe gudugudu meje toun ti bi Bournemouth se kagidi bori.

Oríṣun àwòrán, IAN KINGTON/AFP/Getty Images

Àkọlé àwòrán,

hazard lo jẹ goolu keji fun Chelsea

Oun ati Pedro to wọle ni abala keji ni wọn jẹ goolu mejeji ti Chelsea fi pegede nigba ẹkẹrin ni saa bọọlu ọdun yi.

Chelsea naa ti ni ami mejila bayi ṣugbọn Liverpool fi goolu ṣagba wọn.

Wọn yi ni esi awọn ifẹsẹwonsẹ miran to waye:

  • Brighton 2-2 Fulham
  • Crystal Palace 0-2 Southampton
  • West Ham 0-1 Wolves
  • Everton1-1 Huddersfield