USOpen: Tání Naomi Osaka to gbewúro sójú Serena Williams?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Naomi Osaka se afihan ife ẹyẹ to gba han lẹyin to gbewuro soju Serena Williams
Kaakiri oju opo ayelujara ni orukọ ọdọmọbirin ọmọ ogun ọdun kan ti n ja ranyin ranyin.
Ki se wi pe o jale tabi o wuwa odaran sugbọn o se oun manigbagbe kan pẹlu bi o ti se jẹ obinrin orileede Japan akọkọ ti yoo de asekagba idije Grand slam lawn tennis ti o si gba ife ẹyẹ naa.
Naomi Osaka lorukọ ọdọmọbirin naa oun si ni o se adinagboku fun Serena Williams lati ma gba ife ẹyẹ ẹlẹkẹrinle logun rẹ ninu idije Us Open Grand Slam.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oun idunu ni aseyọri yi jẹ fun Naomi Osaka
Lẹyin pe a mọ wi pe o je ọmọ orileede Japan kini awọn nkan miran ti oi ye ki ẹ mọ nipa ọmọdebirin yi?
Ẹjẹ Amẹ́rika,ti Japan, ati Haiti lo wa lara rẹ
Alawọdudu ni Baba Naomi Osaka,Leonard Francois ti o si jẹ ọmọ orileede Haiti.
Haiti lo dagba si sugbn nigba ti yoo fi lọ si ile ẹkọ giga,Amerika lo ti kawe ni Yunifasiti New York.

Oríṣun àwòrán, @Naomi_Osaka_
Aworan Naomi Osaka,ẹgbọn rẹ Mama ati Baba rẹ
Lẹyin to ari ẹkọ rẹ lo lọ si Japan nibi ti o ti pada iya Naomi,Tamaki Osaka to jẹ ọmọ Japan.
Nigba ti Naomi wa ni ọmọ ọdun mẹta ni awọn obi rẹ gbe lọ si orileede Amerika pẹlu ẹgbọn rẹ obinrin,Mari.

Oríṣun àwòrán, @Naomi_Osaka_
Naomi se afihan asia orileede Japan to jẹ ilu to n soju fun
Ọmọ orileede Japan ati Amerika ni Naomi sugbọn Japn lo n soju fun.
Agbabọọlu Tennis loun ati ẹgbọn rẹ Obinrin Mari
Afiwe kan ti opo ti n sọ nipa Naomi Osaka ati Serena Williams to gbewuro soju rẹ ni pe awọn mejeji ni ẹgbọn obinrin to n gba Tennis.

Oríṣun àwòrán, @Naomi_Osaka_
Naomi Osaka ati ẹgbọn rẹ Mari
Venus loruko ẹgbọn Serena nigba ti orukọ ẹgbọn Naomi si n jẹ Mari
Lori akasọ ipo ti wọn wa ninu ere Tennis lagbaye fun ọdun 2018(WTA Women's Single)Naomi wa ni ipo kọkandinlogun (19th) nigba ti ẹgbọn rẹ Mari si wa ni ipo ọ̀rìnlénígba lé mesan (289th)
Owo Tabua ni Naomi gba pẹlu ife ẹyẹ rẹ akọkọ
Lati igba ti wọn ti n fun oludije ni owo ẹbun asyeori,Naomi Osaka ni yoo gba owo to poju .
$3.8 millionu owo dolla ni Naomi gba eyi to je iye owo to ti poju ti oludije yoo gba ninu idije naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Naomi ni Serena Williams jẹ ẹni ti oun ma n wo gẹgẹ bi awokọse
Serena Williams naa ko sanpa lo ile lasan.$1.85 millionu ni oun naa gba pe o se ipo keji.
Awọn ti wọn gbiyanju de abala to kangun si asekagba naa gba $925,000 owo dolla ni gba mabinu.
Baba rẹ lo kọ ni Tennis gbaa
Igbese Baba Serena Wiliams nipa bi o ti se kọ awọn omobirin rẹ ni Tennis lo jẹ iwuri fun Baba Naomi,Leonard Francois lati ko Naomi ati ẹgbọn rẹ Mari nipa Tennis.

Oríṣun àwòrán, @Naomi_Osaka_
Naomi fi aworan yan yio sita loju opo Twitter lati fi ki Baba rẹ ku ayajọ ọjọ ibi rẹ
Akitiyan rẹ ko ipa ribiribi ninu igbesi aye ọmọ ati bi o ti se wa di ilumọka agbabọọlu Tennis loni.
Sugbọn oun to je iyalẹnu ni pe Leonard kosi ni papa isere ibi ti ọmọ rẹ ti gba ife ẹyẹ Grand Slam akọkọ rẹ.