George Weah: Nàìjírìa fìyà jẹ Ààrẹ Liberia pẹ́lú ikọ̀ rẹ̀

George Weah Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán George Weah kópa nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Nàìjírìa

Aarẹ orilẹede Liberia George Weah pada sori papa ni ọmọ ọdun mọkanlelaadọta nibi to ti kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ pẹlu orilẹede Naijiria lọjọ Iṣẹgun nilu Monrovia.

Ṣugbọn Aarẹ Weah to gboye agbabọọlu to pegede julọ lagbaye lọdun 1995 ko le gba ikọ agbabọọlu orilẹede rẹ silẹ lẹyin ti ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria fiya jẹ wọn pẹlu ami ayo meji si ẹyọkan.

Agbabọọlu tẹlẹ ri Weah to jẹ alawọdudu akọkọ ti yoo gba ami ẹyẹ agbabọọlu to pegede julọ lagbaye wa lori papa fun iṣẹju mọkandinlọgọrin ki wọn to paarọ rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌmọdé tó ń fi ọpọ́n àyò gba ipò

Orilẹede Liberia ṣe agbekalẹ ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ ọhun lati fi adagba jẹẹsi pẹlu nọmba mẹrinla(14) ti Weah wọ nigba ti o n gba bọọlu rọ.

Image copyright Instagram/theliberianinfluence
Àkọlé àwòrán Ààrẹ George Weah fìdí rẹmi pẹ̀lú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Liberia

Henry Onyekuru ati Simeon Nwankwo lo gba ayo meji sawọn fun Nigeria ki agbabọọlu Kpah Sherman to d'ayo kan pada pẹlu pẹnariti.

Weah gba bọọlu fun awọn ikọ bi Monaco, Paris Saint-Germain ati Marseille nilẹ Faranse ati AC Milan orilẹede Italy ki o to fẹyinti.