Salah: Liverpool lè gba ife ẹ̀yẹ UCL àti EPL ní sáà yìí

Mohamed Salah, Neymar, Edison Cavani àti Kylian Mbappe Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Liverpool kojú PSG lórí pápá Anfield

Ẹlẹsẹ ayo fun ikọ Liverpool Mohammed Sallah ti f'ọwọ ṣoya pe Liverpool le gba ife ẹyẹ UEFA Champions League ati ti Premier League papọ ni saa yii.

Liverpool yoo ṣide ipolongo wọn ninu idije Champions league lọjọ Iṣẹgun nigbati wọn ba waako pẹlu Paris Saint Germain ni papa iṣere wọn ni Anfield.

Lọṣẹ to kọja ni onimọ nipa ere bọọlu Gary Neville sọ pe ki Liverpool gbagbe Champions League ki wọn le gbaju mọ Premier League nikan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsun Decides: Adegoke ni òun kò ni lo kọngilá n

Ṣugbọn akọnimọọgba Liverpool Jurgen Klopp ni isọkusọ lọrọ naa, igbagbọ re ni pe ikọ Liverpool to gbangba sun lọyẹ lati gba ife ẹyẹ mejeeji.

Salah naa ti wa kin akọnimọọgba naa lẹyin bayii ninu ifẹsọrọwerọ pẹlu awọn oniroyin ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu PSG.

Liverpool de abala aṣekagba idije Champions League ni saa to lọ nibi ti wọn ti fidi rẹmi lẹyin ti Real Madrid na wọn pẹlu ami ayo mẹta sẹyọkan lati gba ife ẹyẹ naa.

Awon Ifẹsẹ̀wọnsẹ̀ mìíran ti yoo waye

Club Brugge v Borussia Dortmund20:00

Monaco v Atletico Madrid20:00

Barcelona v PSV Eindhoven17:55

Inter v Tottenham Hotspur17:55

FK Crvena Zvezda v Napoli20:00

Galatasaray v Lokomotiv Moscow20:00

Schalke 04 v Porto20:00