Amputee World Cup: Wọ́n na ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà jáde

Agbábọ́ọ̀lù Special Eagles

Oríṣun àwòrán, Mundial De Futbol

Àkọlé àwòrán,

Ikọ̀ Special Eagles gbìyànjú, ṣùgbọ́n omi pọ̀ ju ọkàn lọ

Ikọ agbabọọlu Naijiria ti wọn jẹ akanda eniyan, Special Eagles ti dero ile nibi idije World Amputee Football Federation (WAFF) to n lọ lọwọ ni Mexico.

Idi abajọ ni pe ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria kuna lati gbayo to pọ wọle awọn ikọ alatako, eyi gan an lo jẹ ki wọn kuna lati tẹsiwaju si ipele ẹlẹni mẹrindinlogun.

Ikọ Special Eagles tiẹ gbiyanju lati jawe olubori fun igba akọkọ ninu idije ọhun nigba ti wọn fagba han ẹgbẹ agbabọọlu El Savaldor pẹlu ami ayo kan sodo ninu ifẹsẹwọnsẹ ti isọri Group E ti wọn wa pẹlu Brazil ati Russia.

Ṣugbọn ai leegba ju ami ayokan lọ lo ṣe okunfa bi wọn ti dero ile ati pe Naijiria wa ni ipo kẹta ni isori naa pẹlu ami ayo mẹta lẹyin ti Brazil ati Russia wa loke tente.

Oríṣun àwòrán, Other

Àkọlé àwòrán,

Ikọ̀ Special Eagles ti kùnà láti kópa nínú ìdíje nàá fún ọdún mẹ́ta; 2010, 2012 àti 2014, nítorí ìṣòro àìrówó ná

Ẹwẹ, alubami ni ikọ Brazil na ikọ Special Eagles pẹlu ami ayo 6-0, ti Russia naa si na wọn pẹlu ami ayo mẹta si odo ninu ifẹsẹwọnsẹ meji akọkọ ti wọn gba.

Ikọ̀ Special Eagles ṣagbe láti díje nínú ife ẹ̀yẹ àgbáyé`

Níṣe ni ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù àwọn ti wọ́n gé l'ẹ́sẹ̀ l'órílẹ̀-èdè Nàìjíríà n ṣagbe lórí ẹ̀rọ ayélujára láti rí owó kójọ fún ìrìnàjò wọn láti kópa níbi ìdíje ife àgbáyé Amputee World Cup tó ku ọ̀sẹ̀ mẹ́ta péré kò bẹ̀rẹ̀.

Ikọ̀ Special Eagles ti kùnà láti kópa nínú ìdíje nàá fún ọdún mẹ́ta; 2010, 2012 àti 2014, nítorí ìṣòro àìrówó ná.

Èyí ló mú kí agbábọ̀ọ́lù fún ikọ̀ Arsenal tó jẹ́ ti àwọn tí wọ́n gé l'ẹ́sẹ̀, Arsenal Amputee FC, Michael Ishiguzo, tó n gbé ní ìlú London, nígbà tó gbọ́ nípa wàhálà nàá, bẹ̀rẹ̀ ètò agbe ṣíṣe lórí ẹ̀rọ ayélujára GoFundMe, láti le kó ẹgbẹ̀rún méjìdínláàdọ́rin Dọla jọ́ fún wọn.

Ishiguzo sọ fún BBC Sport pé ''àwọn géndé ọkùnrin yìí ti ṣiṣẹ́ kára-kára, tó sì jẹ́ wí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni wọ́n ti kùnà láti kópa nínú ìdíje Ife ẹ̀yẹ Àgbáyé, nítorí ó dà bí ẹni pé ìjọba, àti àwọn iléèṣẹ́ nla kò bìkítà fún wọn.

Oríṣun àwòrán, Other

Àkọlé àwòrán,

Wọ́n ti rí Pọ́nhùn márùnlélọ́gọ́fà kójọ láàrin ọjọ́ kan tí ìpolongo nàá bẹ̀rẹ̀ lórí ẹ̀rọ ayélujára

''Ìnira wọn n ta mí lára. Wọn kò rí àtilẹyìn gbà láti ibikíbi.

''Níṣe ni wọ́n n fi owó ara wọn gbọ́ bùkátà eré ìdárayá nàá ní àfikún sí kìrà-kìtà wọn láti pèsè òunjẹ fún ẹbí wọn."

Ìrètí ikọ̀ Special Eagles ni láti rí owó kó jọ fún ríra tíkẹ́ẹ́tì ọkọ̀ bàálù, owó oúnjẹ, àti àwọn nkan mìí tí wọ́n nílò láti kópa níbi ìdíje nàá tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù Kẹwàá.

Oríṣun àwòrán, Other

Àkọlé àwòrán,

Michael Ishiguzo tó n gbá bọ́ọ̀lù fún Arsenal Amputee FC l'óún ṣètò ìkówójọ fún ikọ̀ Special Eagles ti Nàìjíríà

Ishiguzo tó ti jẹ́ agbábọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀ rí ní ìlú Eko ko ìjàmbá eléyìí tó mú òpin dé bá iṣẹ́ tó yàn láàyò lọ́dún 1997 èyí ló sì mú kí wọ́n gé ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀.

Ìgbà tó yá ni ó yí ojú sí eré onírin Javelin jújù àtàwọn eré ìdárayá mìíràn kó tó padà sí bọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá.

Àkọlé fídíò,

#Adetutu Alabi OJ: Mo ti gba kámú lórí ilà ojú mi