Premier League: Arsenal àti Liverpool gbéná wojú ara wọn

Alexandre Lacazette

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Arsenal àti Liverpool gbéná wojú ara wọn

Eegun k'eegun ni ifẹsẹwọnsẹ Arsenal pẹlu Liverpool ninu idije Premier League lẹyin ti ere bọọlu naa pari si omi alayo kọọkan ni papa iṣere Emirates nilu London.

Liverpool lo kọkọ siwaju lẹyin ti James Milner gbayo wọle ni kete ti ifẹsẹwọnsẹ naa le diẹ ni wakati kan.

Ṣugbọn ikọ Arsenal ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe Liverpool ko na wọn mọle.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ifẹsẹwọnsẹ naa ku iṣẹju mẹjọ ko pari ni ẹlẹsẹ ayo Alexandre Lacazette gbayo sawọn ti ere bọọlu naa fi di omi.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Arsenal àti Liverpool gbéná wojú ara wọn

Ikọ Arsenal ko lanfani lati na Liverpool lati igba ti Klopp ti di akọnimọọgba wọn titi digba ti Arsene Wenger fi dagbere fun Arsenal.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Arsenal kojú Liverpool ní Emirates

Ọpọ ololufẹ ere bọọlu lo wo ifẹsẹwọnsẹ ọhun kaakiri agbaye.

Arsenal fiya jẹ Fulham

Aaron Ramsey fakọyọ bi Arsenal ṣe lu Fulham la lu bolẹ lati jawe olu bori ni ifẹsẹwọnsẹ wọn ni Premier League to n lọ lọwọ pẹlu ami ayo marun si ẹyọkan.

Alexandre Lacazette naa gba ayo meji wọle ti Pierre-Emerick Aubameyang na gba bọọlu wọ awọn fun igba meji ọtọtọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Arsenal gba ami ayo kẹrin wọle ni idije Premier League fun igba akọkọ ni saa yi pẹlu aṣeyọri wọn ni Craven Cottage

Iṣẹju kẹtadinlaadọrin ni Ramsey wọle ti o si gba ami ayo kan wọle ki o to pe iṣẹju kan.

Diẹ bayi lo ku ki Fulham wọ ijakulẹ (relegation) bi o ṣe wa ni ipo mẹtadinlogun.