Real Madrid: A ti kọ̀wé gbélé rẹ fún Julen Lopetegui

Real Madrid

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Kò ju oṣù mẹ́rin ti Real Madrid gba akọ́nimọ̀ọ́gbá Julen Lopetegui ti wọ́n ti ní kó lọ rọọ́ kún nílé.

Ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid ti fi Santiago Solari rọpo Julen Lopetegui gẹgẹ bi akọnimọọgba tuntun.

Ninu atẹjade ti Real Madrid fi sita, Solari yoo wa ni ipo akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu naa titi wọn yoo fi ri ẹni to koju osuwọn lati tukọ wọn.

Iroyin fikun wi pe akọnimọọgba tuntun naa kii se gbajugbaja ti awọn eniyan mọ l'agbo ere bọọlu ilẹ Spain.

Ni bayii solari yoo tukọ ẹgbẹ Real Madrid lati kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹrin pẹlu Malilla, ninu idije Copa Del Rey, Real Valladolid ati Celta Vigo ninu idije League.

Nigba ti wọn yoo ma koju Viktoria Plzen ti ilẹ Czech ninu idije Champions League.

Real Madrid: Ta ló tóo gbé wọn dé èbúté ògo nínú Premiere League?

Àmì ayò márùn ún sí ọ̀kan ni Barcelona fi gbewúro sójú Real Madrid ni El Classico.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Won ko fun Julen Lopetegui laaye ju osù merin lọ lati tukọ Real Madrid

Eyi jẹ ọkan lara idi ti wọn fi ni ki akọnimọogba wọn, Julen Lopetegui maa lọ sile rẹ pada ni eyi to sọ wọn di ẹni to n wa akọnimọọgba tuntun bayii.

Oriṣiiriṣi àwọn akọnimọogba lo ti n fifẹ han lati tukọ ẹgbẹ agbabọọlu yii siwaju ninu idije premiere league. Idije mii ti wọn ni niwaju ni pẹlu Melilla ninu idije Copa del Rey lalẹ ọjọ'Ru.

Ta ni adé yìí yóò wọ orí rẹ́?

Ọ̀kan pataki lara awọn ti wọn n foju si lara lati wọ bata akọnimọọgba tuntun fun Real Madrid ni Santiago Solari.

Santiago Solari ni ẹgbẹ agbabọọlu na yan lati dile mu fun wọn gẹgẹ bii akọnimọọgba titi wọn yoo fi gba ẹlomii rọpo Julen.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Santiago ni ẹnu n kùn julọ pe o ṣeeṣe ki ade yii ṣimọ lori

Santiago jẹ ọkan lara agbabọọlu Real Madrid tẹlẹ ko to lọ maa kọni mọọgba ni Madrid 'B' ki wọn to pèé kó wa ba wọn di real Madrid mu fun igba diẹ yii.

Ọdun 2013 ni Solari darapọ mọ ẹgbẹ yii to si mọ tifun-tẹdọ rẹ̀.

Antonio Conte:

Antonio jẹ ọkan pataki lara awọn agba akọnimọọgba ninu ere bọọlu alafẹsẹgba.

Ọpọlọpọ gbà pé o ni iriri to le gbé ẹgbẹ Real Madrid soke ninu idije yii. Lati igba ti ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ti daa duro ni ko tii niṣẹ mii to n ṣe.

Iroyin to n kàn lọwọ ni pe Antonio ọmọ Italy yii ti ṣetan lati ṣiṣẹ pẹlu wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Conte ko i niṣẹ mii lati igba ti Chelsea ti daa duro

Conte ti gba ife ẹyẹ League lẹẹmeji ri pẹlu Chelsea ati Juventus ni eyi to fi iriri rẹ han pe o to iṣẹ naa ṣe.

Jose Mourinho:

O jẹ agba ọjẹ akọnimọọgba to ti ṣiṣe pẹlu Real Madrid ri.

Ọmọ Pọtugi yii ni ko wu oun lati pada si Real Madrid ṣugbọn iroyin ti a n gbọ ni pe, wọn ti n wo apa ọdọ rẹ naa wo boya o le gbe Real Madrid de ebute ogo lasiko yii.

Manchester United ni Mourinho ti n ṣiṣẹ bayii. Ọdun 2010 si 2013 lo fi jẹ akọnimọọgba fun Real Madrid.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Oju Real Madrid tun ti wa lara Jose Mourinho lasiko yii

Arsene Wenger:

Arsene Wenger fipo rẹ silẹ kuro ni Arsenal lẹyin ogun ọdun o le meji to ti n ba wọn ṣiṣẹ.

Lati igba to ti kuro ni oun naa ko tii niṣẹ miran di asiko yii.

O jẹ ọkan lara awọn agba ọjẹ akọnimọọgba ni Yuroopu ni eyi ti ọkan awọn Real Madridi lè balẹ pẹlu fun ilọsiwaju.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Wenger naa koi tii niṣẹ miran latigba to ti kuro ni Arsenal

Ki ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn ní Real Madrid?

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Omi ti tẹyin wọ igbin lẹnu fun Lopetegui

Ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid ti gbà iṣẹ́ lọ́wọ́ akọnimoogba wọn Julen Lopetegui.

Ikede yi waye lẹyin osu mẹrin ati abọ to gba iṣẹ akọnimoogba ẹgbẹ La Liga ohun.

Eyi ni igba ẹlẹkeeji ti iṣẹ yoo bọ lọwọ Lopetegui.

Real Madrid to ti gba liigi fun igba mẹsan ko ṣe daada lẹnu ọjọ mẹta yi labẹ akoso Lopetegui.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Eyi ni igba ekeji ti iṣẹ yoo bọ lọwọ Lopetegui

Ikede iyọniniṣẹ rẹ́ ti wọn fi si oju opo Twitter wọn salaye pe Santiago Solari to jẹ agbabọọlu ẹgbẹ naa tẹlẹ ri ati akonimoogba ikọ keji Real Madrid ni yoo gba ipo rẹ titi ti wọn yoo fi kede eni ti yoo rọpo rẹ.

Ẹgbẹ agbabọọlu na salaye pe aisedeede wa ''laarin awọn osiṣẹ ẹgbẹ naa ti esi ti awọn n ri''

Ipo kẹsan ni wọn wa lori afara liigi.

Ọrọ ro naa doju rẹ pẹlu ifidirẹmi El Classico

Luis Suarez jẹ goolu mẹta lati da kun iṣoro akọnimọgba ikọ Real Madrid , Julen Lopetegui, ninu ifẹsẹwọnsẹ El Classico to lamilaka lọjọ aiku.

Julen Lopetegui ati awọn agbabọọlu rẹ ko ri ju esi goolu kan dapada ninu maarun ti Barcelona gba sinu awọn wọn.

Ni bayi, a ti ma padanu iṣẹ Julen Lopetegui yoo ku si ọwọ Ọlọrun pẹlu bi awọn alatako ẹgbẹ wọn ti ṣe doju ti wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Aisinile Messi ko tiẹ yọlẹ pẹ́lu bi Suarez ṣe jẹ goolu mẹta

Phillipe Coutinho lo kọkọ gba goolu wọle ni abala ikini ifẹsẹwọnsẹ naa lẹyin ti Luis Suarez jẹ gbesilẹgbasile wole fun goolu elekeji.

Real Madrid ja fita fita ni abala keji ti wọn si ri goolu kan jẹ lati ọwọ Marcello to faya sọ bọọlu kale ki o to gba wole pẹlu ẹsẹ ọtun rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ẹpa ko boro mọ

Kaka ki ewe agbọn Barcelona dẹ, niṣe ni o le koko si ti wọn si fi goolu mẹta ọtọọto dakun wahala Real Madrid.

Ninu goolu mẹta ohun,Luis Suarez jẹ meji ti Arturo Vidal si kasẹ eto n lẹ pẹlu goolu ẹlẹkaarun.

Pẹlu esi yi, Real Madrid ti bọsi ipo kẹsan lori afara liigi ti Barcelona si le tente lori afara.

Àkọlé fídíò,

#Adetutu Alabi OJ: Mo ti gba kámú lórí ilà ojú mi