BBC African Footballer 2018: Mohamed Salah wà lára àwọn tí yóò du àmì ẹ̀yẹ

Medhi Benatia (Morocco), Kalidou Koulibaly (Senegal), Sadio Mane (Senegal), Thomas Partey (Ghana) ati Mohamed Salah (Egypt) Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Medhi Benatia, Kalidou Koulibaly, Sadio Mane, Thomas Partey ati Mohamed Salah (ti wọn fi aworan wọn han lati apa osi si ọtun) ni wọn yan fun ami ẹyẹ naa

Wọn ti gbe orukọ awọn agbabọọlu marun un ti wọn ṣa lẹsa, lati du ami ẹyẹ '2018 BBC African Footballer of the Year' jade.

Awọn ti wọn yan fun ami ẹyẹ tọdun yii ni Medhi Benatia (Morocco), Kalidou Koulibaly (Senegal), Sadio Mane (Senegal), Thomas Partey (Ghana) ati Mohamed Salah (Egypt).

Ibo didi lori ẹrọ ayelujara lati yan agbabọọlu to pegede yoo bẹrẹ lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kọkanla, laago meje ti yoo si wa si opin ni ọjọ keji, oṣu kejila laago mẹjọ alẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAyàwòrán Obama: Ọ̀pọ̀ ìgbà ni èmi àti ìyá mi pa èbi mọ́nú kí n tó jẹ́ èèyàn

Wọn yoo kede esi ibo naa, ninu akanṣe eto lori BBC World News lọjọ kẹrinla, oṣu kejila, laago marun abọ irọlẹ.

Awọn akọsẹmọṣẹ ere bọọlu lo ṣa orukọ awọn agbabọọlu naa.

Atamatase ẹgbẹ Liverpool, Mohammed Salah lo gba ami ẹyẹ ọdun to kọja ti Jay-Jay Okocha, Michael Essien, Didier Drogba, Yaya Toure ati Riyad Mahrez naa wa lara awọn to ti gba ami ẹyẹ naa nigba kan ri.

Awọn to n du ami ẹyẹ naa

Adiẹyin mu fun ẹgbẹ Juventus, Benatia, to jẹ ọmọ ọdun mọkanlelọgbọn, gba liigi ẹlẹrin lera lọdun yi -o gba meji pẹlu Bayern Munich, mẹji pẹlu Juve ti o si jẹ wi pe oun ni balogun ikọ Morocco ni idije ife agbaye to kọja.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán A ju ara wa lọ, ijakadi kọ

Adiẹyin mu Napoli Koulibaly, ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn, kopa ti rẹ ninu faa kin fa laarin ẹgbẹ rẹ pẹlu Juventus fun ami ẹyẹ fun ami ẹyẹ Serie A to fi mọ bi wọn ti ṣe jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Juventus. O kopa ninu gbogbo iṣẹju ọ̀rìnlénígba din mẹjo ti Senegal fi tasẹ ninu idije ife ẹyẹ agbaye.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Agbara ju agbara lọ lori papa

Atamatase Liverpool Mane, to jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn, naa kopa ninu gbogbo ifẹsẹwọnsẹ Senegal ni idije ife ẹyẹ agbaye.

Koda oun ni balogun ikọ naa ti o si jẹ goolu ninu ifẹsẹwọnsẹ Senegal pẹlu Japan.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Akọṣẹmọṣẹ yatọ si awọn àsáréwọ̀ lori papa

O jumọ jẹ ẹni ti o jẹ goolu to pọju lọ ninu idije Champions League ọdun to kọja pẹlu goolu mẹwa rẹ to jẹ fun Liverpool to fi mọ eleyi to jẹ ninu ami ayo mẹta si ookan ti Liverpool fi fidirẹmi lọwọ Real Madrid ninu aṣekagba.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Eeguin ju eegun lọ ninu ere bọọlu

Agbabọọlu arin fun Atletico Madrid Partey, to jẹ ọmọ ọdun mẹẹdọgbọn, fi ẹsẹ rẹ mulẹ gẹgẹ bi ọkan lara awọn agbabọọlu ikọ ti Diego Simone n dari.Akosilẹ wa wi pe oun naa kopa ninu asekagba Europa liigi ti Atletico ti bori Marseille. O jẹ goolu fun orileede Ghana ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ pẹlu Japan ati Iceland.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Nini afojusun àwọn ti bọọlu a wọ̀ kọja ọjọ ori

Agbawaju Liverpool Salah, to jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn lo gba buutu goolu Premier League fun pe o jẹ goolu mejilelọgbọn losu kaarun ti o si jẹ goolu mẹwa bi ti Mane ninu idije Champions League.

Oun lo jẹ goolu Egypt mejeeji ninu idije ife agbaye to se deede ida ogoji ninu ọgọrun iye goolu ti Egypt jẹ ni idije naa.