EFCC: Irọ́ ni Fayoṣe ń pa, àwọn ilé rẹ̀ gangan la tì pa

Image copyright Olasunkanmi Ogunmuko

Ajọ EFCC ti ti awọn ile kan pa ni Ado Ekiti ti wọn funra si pe o jẹ ti Gomina ana ni ipinlẹ Ekiti Ayo Fayose.

Ṣugbọ́n ọkan lára àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Ipinlẹ Ekiti Samuel Omotosho ti ni oun ni oun ni ọkan lara awọn ile naa.

O ni ile oun ti EFCC ti pa naa wà ni Ọja Okeṣa ni Ado-Ekiti.

Ile epo kan to wa ni agbegbe Akute ni Ipinlẹ Ogun wa lara awọn ile ti wọn ti pa naa.

Oun lo mu ki Fayose gbe ọrọ naa lọ ori Twitter nibi to ti fi ẹsun kan ajọ naa pe awọn ile-onile ni EFCC n ti pa.

Fayose ni EFCC tun ti ile kan to wa ni adugbo Gana ni Maitama, Abuja.

Omotosho ni, "EFCC n fi oju ẹtọ mi gbolẹ wọ́n si n halẹ mọ mi.

Kini EFCC n sọ?

Ṣugbọn agbẹnusọ ajọ EFCC, Toni Orilade ni, Fayose kan n lo ọpọlọ awọn ara ilu lasan ni.

Orilade ni, "Ẹ ranti wipe ẹjọ ti wa nile ẹjọ, ko si idi to fi yẹ ki Fayose maa lọ yọ ẹnu si awọn oniroyin. To ba ni nkan ti ko tẹ lọrun, ko gbe wa sile ẹjọ. To ba jẹ tootọ ni pe ile-onile ni ajo EFCC n ti pa, ṣe bi awọn ti o ni ile naa ko ti i ku? Kilo de to fi di agbẹnusọ fun wọn. Ti EFCC ba ti ile-onile, ki ẹni to nile naa jada, tabi ko gbe ọrọ naa lọ ile ẹjọ."

Image copyright Olasunkanmi Ogunmuko

Fayose n jẹjọ niwaju Ile ẹjọ fun ẹsun ṣiṣe owo ti o to bilionu meji naira ati diẹ baṣubaṣu.

Image copyright Olasunkanmi Ogunmuko
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLere Ọlayinka: Ayo Fayose sí wà ní gbaga àwọn EFCC

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Ta ló dà bíi Ọlọ́run Fayoṣe' lorin tó ń jáde nílé ẹjọ́