Kí ló ṣẹlẹ̀ nínú ìdíje Premier League? Man City, Liverpool jáwé olúborí

David Silva Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Góòlù tí David Silva jẹ ní ìbẹ̀rẹ̀ ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ fún Manchester City ní bóòlù kẹẹ̀jọ rẹ̀ nínú sáà yíì

Manchester City tẹ̀síwájú pẹ̀lú sísíwájú ìdíje Premier League, Liverpool tó jé ẹgbẹ́ kẹjì nínú ìdíje náà jáwé olúborí, Manchester United sí gbá ọ̀ọ̀mì nílé nígbà tí Claudio Ranieri bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ ní Fulham pẹ̀lú ìṣẹ́gun.

Ẹgbẹ́ City tó je ìdíje náà ní ọdún tó kọjá, jẹ góòlù mẹ́ta nínú ìṣẹ́jú mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n àkọ́kọ́ ní pápá ìṣeré London- nípasẹ̀ David Silva, Raheem Sterling àti Leroy Sane, tí Sane s[fi ẹlẹ́ẹ̀kẹẹ̀rin kún-un nígbà tó kù díẹ̀ kí eré parí - eléyìí mún kí ẹgbẹ́ Pep Guardiola ṣẹ́gun West Hampẹ̀lú àmìn ayò 4-0 .

Liverpool sì dúró lẹ́yìn Man City pẹ̀lú àmì ayò mẹ́jì lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n naWatford mọ́lé ní 3-0 , níbi tí Mohamed Salah, Trent Alexander-Arnold àti Roberto Firmino ti jẹ góòlù kọ̀ọ̀kan bótilẹ̀jẹ́pé ikọ̀ Reds pàdánù agbábọ́ọ̀lù kan pẹ̀lú lẹ̀yìn tí wọ́n lé Jordan Henderson jáde.

Ẹgbẹ́ Jose Mourinho, Manchester United, pàdánùn àmì ayò mẹ́jì nígbà tí wọ́n gbá ọ̀ọ̀mì 0-0 pẹ̀lú Crystal Palace(ẹgbẹ́ tí kọ̀ tíi ṣẹ́gun nínú ìfẹ́sẹ̀wọ́nsẹ̀ mẹ́jọ) níOld Trafford.

Wọ́n yan Ranieri, tó jẹ ìdíje líígì ilẹ̀ Gẹ́ẹ̀sì nígbà tó ń ṣe akọ́nimọ̀ọ́gbá ní Leicester City, ní akọ́nimọ̀ọ́gbá Fulham nínú oṣù yìí, ó sì bá Southampton fàá nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ kan tó lágbára.

Fulhamló kọ́kọ́ jẹ́ góòilù nípasẹ̀ Stuart Armstrong, nígbà tí Aleksandar Mitrovic bá jẹ Southampton ayò kan, Andre Schurrle sì tú bá ẹgbẹ́ London náà jẹ ayò kan síi. Nígbà tí Armstrong gbá bọ́ọ̀lù rẹ̀ kẹjì wọlé, ayò bá di 2-2, ṣùgbọ́n góòlù tí Mitrovic ló bá Fulham ṣẹ́gun Southampton tí ayò sì parí ní 3-2. Èsì ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà ti gbé Fulhamsí òkè Huddersfield láti ìsàlẹ̀ ìdíje líìgì náà.

Gylfi Sigurdsson ló je àmì ayò kan soso nígbpà tí Everton na Cardiff City ní 1-0 ní pápá ìṣeré Goodison Park.

Ó dà bí ẹni pé Brighton fẹ́ ṣẹ́gun nígb[pa tí Glenn Murray kọ́kọ́ je, tí wọ́n lé ọmọ ikọ̀ Leicester City, James Maddison, jáde lẹ́yìn ìsẹ́jú mẹ́jìdílọ́gbọ̀n (28) sí ìgbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ eré - sùgbọ́n ikọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́wàá (10) Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Tottenham gbo ewúro sí ojú Chelsea pẹ̀lú àmì ayò 3-1.

Related Topics

Àwọn ojú òpó ayélujára tí ó jọ èyí

BBC kò mọ̀ nípa àwọn nnkan tí ó wà nínú àwọn ojú òpó ayélujára ní ìta