AWCON: Nàìjírìa gba ife ẹ̀yẹ AWCON fún ìgbà kẹsàn-án

Super Falcons Image copyright @NGsuper_falcons
Àkọlé àwòrán Ìdùnnú ṣubú layọ̀ fún àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ki awọn agbabọọlu ikọ Super Falcons ku oriire bi wọn ṣe jawe olu bori ninu aṣekagba idije ife ẹyẹ ilẹ Afirika ti àwọn obinrin lọjọ Abamẹta

Buhari fi idunnu rẹ han lori bi ikọ agbabọọlu naa ṣe gba ife ẹyẹ idije naa nigba kẹsan-an .

Nàìjírìa fakọyọ nínú ìdíje AWCON

Nàìjírìa ti gba ife ẹ̀yẹ ere bọọlu awọn ilẹ Afirika AWCON lẹ́ẹ̀kẹsàn an lẹyin ti wọn na South Africa pẹlu ami ayo mẹrin si mẹta nínú ifẹsẹwọnsẹ aṣekágba ìdíje náà.

Ọọmi odo sodo ni wọn ta nigba ti iṣẹju aadọrun akọkọ kọkọ pari, lẹyin naa ni wọn tun gba bọọlu fun ọgbọn iṣẹju miran.

Ṣugbọn ko sẹni to tun rayo gba wọle ara wọn lẹyin ọgbọn iṣẹju naa, lọrọ ba di wo mi ki n gba siọ ti wọn n pe ni pẹnariti.

Nibi pẹnariti ri gan ni Naijiria ti fagba han South Africa pẹlu ami ayo mẹrin si mẹta 4-2.

Ikọ agbabọọlu Naijiria ti gba ife ẹyẹ naa lẹẹmẹsan an ọtọtọtọ bayii, nigba ti alatako wọn South Africa ko tii gba ri rara.

Image copyright @NGsuper_falcons
Àkọlé àwòrán Ìgbà kẹsàn-án rèé tí wọn yóò gba ife ẹ̀yẹ náà

Ikọ Super Falcons ko tii fidi rẹmi ri ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije ife ẹyẹ ọhun, ṣugbọn South Africa ti kuna lẹẹmẹrin ti wọn ti kopa ninu aṣekagba idije naa

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Igba keji ree ti Naijiria ati South Africa yoo waako ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije ife ẹyẹ ere bọọlu awọn obinrin nilẹ adulawọ.

Image copyright Instagram/Super Falconspage
Àkọlé àwòrán Idije Awcon

Ikọ Super Falcons lo jawe olubori pẹlu ami ayo meji sodo nigba ti wọn pade ninu idije ti ọdun 2000 nilu Johannesburg lorilẹede South Africa.

Ẹ rant i wi pe South Africa lu Naijiria pẹlu ami ayo kan sodo ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ awọn mejeeji ninu idije ti ọdun yii lorilẹede Ghana.