Ballon D'or 2018: Modric jáwé olú borí, Ronaldo, Messi fìdí r'ẹmi

Luka Modric Image copyright FRANCK FIFE

Agbabọọlu aarin gbungbun papa Luka Modric to jẹ ọmọ orilẹede Croatia ló gba àmì ẹ̀yẹ Ballon D'or fun ọdun 2018 lẹ́yìn tí Lionel Messi àti Cristiano Ronaldo.

Ní ìlú Paris ni ayẹyẹ ọhun ti waye lọsan ọjọ́ Aje.

Fún igba akọkọ ni ọdun mẹwàá, Messi ko sí ninu awọn mẹta akọkọ. Modric wa ni ipo kinni, Cristiano Ronaldo ni ipo keji, Antoine Griezmann ni ipo kẹta, ti Kylian Mbapeé si wa ni ipo kẹrin. Ipo karun un ni Messi wa.

Image copyright FRANCK FIFE
Àkọlé àwòrán ssi ko sí ninu awọn mẹta akọkọ

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIkọ̀ Super Falcons kijó mọ́lẹ̀

Kini ami ẹyẹ ballon d'Or da le lori?

Akọroyin ere bọọlu ọmọ orilẹede France kan, Gabriel Hanot lo kọkọ gbe ero nipa Ballon d'Or kalẹ lọdun 1956.

George Weah, agbabọọlu ọmọ orilẹede Liberia to ti di aarẹ bayii ni agbabọọlu akọkọ ti yoo gba ami ẹyẹ naa lai kii ṣe ọmọ ilẹ Yuroopu. Ni ọdun 1995 ti anfani ṣi silẹ fun awọn ọmọ ilẹ agbaye miran lati gbaa ni weah gba ami ẹyẹ yii, nigba ti o n gba bọọlu jẹun ni ẹgbẹ agbabọọlu AC Millan

Awọn agbabọọlu wo lo tii gbaa julọ?

Lionel Messi, lati orilẹede Argentina ati ẹgbẹ agbabọọlu barcelona pẹlu Cristiano Ronaldo ti orilẹede Portugal ati ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid tẹlẹ ki o to darapọ mọ Juventus ni ọdun 2018 ni wọn n pin ami ẹyẹ yii mọ ara wọn lọwọ lati nnkan bii ọdun mẹwa sẹyin.

Ṣaaju ninu ọdun 2018, ajọ to n ri si ere bọọlu afẹsẹgba lagbaye, FIFA fun Modric ami ẹyẹ agbabọọlu to pegede julọ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọrọ lori Ballon D'or

Bẹẹ ni oun naa lo gba ami ẹyẹ agbabọọlu to n dantọ julọ ninu idije ife ẹyẹ agbaye to waye lorilẹede Russia ninu oṣu kẹfa.

Orilẹede Croatia lo ṣepo keji ninu idije ife ẹyẹ agbaye naa, nigba ti France jawe olubori.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọrọ lori Ballon D'or

Awọn wo ni wọn fi orukọ wọn silẹ fun ami ẹyẹ ọhun lọdun yii?

Lootọ, Luka Modric lee lewaju awọn ti wọn n du ami ẹyẹ yii ṣugbọn awọn ti yoo ba du u niwọnyii:

1.Sergio Aguero (Manchester City),

2.Alisson Becker (Liverpool),

3.Gareth Bale (Real Madrid),

4.Karim Benzema (Real Madrid),

5. Edinson Cavani (PSG),

6.Thibaut Courtois (Real Madrid),

7.Cristiano Ronaldo (Juventus),

8.Kevin De Bruyne (Manchester City),

9. Roberto Firmino (Liverpool),

10.Diego Godin (Atletico Madrid),

11.Antoine Griezmann (Atletico Madrid),

12.Eden Hazard (Chelsea),

13.Isco (Real Madrid),

14.Harry Kane (Tottenham),

15.N'golo Kante (Chelsea),

16.Hugo Lloris (Tottenham),

17.Mario Mandzukic (Juventus),

18.Sadio Mane (Liverpool),

19.Marcelo (Real Madrid),

20.Kylian Mbappe (PSG),

21.Lionel Messi (Barcelona),

22.Luka Modric (Real Madrid),

23.Neymar (PSG),

24.Jan Oblak (Atlético Madrid),

25.Paul Pogba (Manchester United),

26.Ivan Rakitic (Barcelona),

27.Sergio Ramos (Real Madrid),

28.Mohamed Salah (Liverpool),

29.Luis Suarez (Barcelona),

30.Raphael Varane (Real Madrid).

Ṣùgbọ́n ọpọ ṣi gbagbọ pe ẹlẹsẹ ayo Cristiano Ronaldo ni ami ẹyẹ Ballon D'or 2018 tọ si lẹyin to gba ife ẹyẹ UEFA Champions League pẹlu Real Madrid ko to darapọ mọ ikọ Juventus.