Àwọn olólùfẹ́ Chelsea kọrin ẹlẹ́yàmẹ̀yà ni pápá ìṣeré

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Àwọn ololufẹ Chelsea n kọrin abuku

Ajọ kan to n gbogun ti idẹyẹsi, Fare, ti sọ pe awon ololufe boolu kan n lo bi nkan se ri ni agbo oselu ile Geesi lati maa deyesi awọn mi i.

Eyi waye leyin ti egbe agbaboolu Chelsea bu enu ete lu bi awon kan lara awon ololufe re se kọ orin ọ̀tẹ̀, orin ideyesi lasiko ti Chelsea ati egbe agbaboolu MOL Vidi ta ọmi ayo meji-meji ni Hungary l'alẹ Ojobo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù parọ́ ikú mọ́ agbábọ́ọ̀lù rẹ̀ láti wọ́gilé ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀

Ni ibere ọsẹ yii, awon ololufe egbe agbaboolu Chelsea meerin ni won fi ofin de leyin ti won fi eebu eleyameya bu Raheem Sterling.

Bakan naa ni agbenusọ Chelsea kan, sọ pe awọn orin eebu ti awon ololufe awon kọ bu awon ololufe Tottenham 'd'ojuti egbe Chelsea.''

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Inu Chelsea kò dun si orin ọtẹ tawọn ololufẹ wọn kọ

Abọ iwadi ajo Watchdog Her Majesty's Inspectorate of Constabulary kan tile so pe lati igba ti Ile Geesi ti bere igbese lati kuro ninu ajo isokan awon alawo funfun, EU, l'odun 2016 ni wahala eleyameya ti bere ni ile Geesi, to si seese ko tun po si l'odun 2019 ti Ile Geesi ba kuro patapata ninu EU.

Ajo to n mojuto boolu gbigba nilu Yuroopu, Uefa, so pe oun n duro de aabo lati odo adari ayo to mojuto idije Europa League to waye l'Ojobo, ko to pinnu igbese to ye lati gbe lori iwa ti awon ololufe Chelsea hu.

Iroyin tile fidire mule pe oludasile egbe agbaboolu Chelsea, Abramovich, ti na opolopo owo ara re lati gbogun ti iwa eleyameya ni Stamforf Bridge.

Bakan naa, l'odun to koja, Chelsea koro oju si iwa eleyameya ti awon ololufe won hu lasiko ti won fi jawe olubori ninu idije kan ti won ni pelu Leicester.

Nise ni awon ololufe Chelsea lo orin kan nipa atamatase won, Alvaro Morata, lati bu alatako won lati London, Tottenham, eyi to je pe eya Jew lo poju ninu awon ololufe re.

Ati wi pe afojusun egbe agbaboolu Chelsea ni lati maa da awon ololufe re l'eko nigba gbogbo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption2016 ni Angel kọ́kọ́ gbé àwo orin rẹ̀ síta láti fi bèrè ìdí tí òun fi yàtọ̀
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Mo ti gba kádàrá lórí bí Ọlọrun ṣe dá mi'