BBC African Footballer: Salah tún fẹ́ gba àmì ẹ̀yẹ̀ lọ́dún 2019

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBBC African Footballer: Salah gba àmì ẹ̀yẹ̀ lẹ́ẹ̀kan síi
Mohammed Salah
Àkọlé àwòrán Mohammed Salah lo tun gbami ẹyẹ BBC

Mohamed Salah lo gba ami ẹyẹ agbabọọlu ilẹ Afirika to pegede julọ fun ọdun 2018 (BBC African Footballer of the Year).

Salah to jẹ ọmọ orilẹede Egypt to si n gba bọọlu fun ikọ Liverpool nilẹ Gẹeṣi naa lo gba ami ẹyẹ ọhun lọdun to lọ.

Salah to jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlọgọn gba ami ẹyẹ naa mọ Medhi Benatia, Kalidou Koulibaly, Sadio Mane ati Thomas Partey lọwọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba ti o n ba BBC sọrọ, Salah ni inu oun dun lati gba ami ẹyẹ naa lẹẹkan si.

Koda o ni inu oun yoo dun gan an t'oun ba tun le rii ami ẹyẹ naa gba lọdun to mbọ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ami ẹyẹ BBC

Salah gba goolu mẹrinlelogoji sawọn fun Liverpool ni saa ere bọọlu afẹsẹ̀gba to lọ, lẹyin to kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ mejilelaadọta.

O tun fakọyọ ninu idije Champions League bi Liverpool ti kopa ninu aṣekagba idije ọhun.