Premier League: Man City padà sípò kínní lẹ́yìn tí wọ́n na Everton

Awọn agbabọọlu Man City Image copyright Twitter/Manchester City FC
Àkọlé àwòrán Man City na Everton

Ikọ agbabọọlu Manchester City ti pada soke ninu idije Premier League lẹyin ti wọn na ẹgbẹ agbabọọlu Everton pẹlu ami ayo mẹta sẹyọkan.

Golu meji ni ẹlẹsẹ ayo Gabriel Jesus gba wọle ki Raheem Sterling to fọba le pẹlu ayo kan si.

Image copyright Twitter/Manchester City FC
Àkọlé àwòrán Raheem Sterling fakọyọ

Bo tilẹ jẹ pe Dominic Calvert-Lewin dayo kan pada fun ikọ Everton, Man City jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun lai si wahala kankan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Jesus ti n tiraka lati fakọyọ lẹyin to kuna lati gbayo sawọn ninu ifẹsẹwọnsẹ mọkanla to kopa ninu rẹ ninu idije Premier League.

Ṣugbọn o ṣalaye pe mama oun to ti de si Ilẹ Gẹeṣi bayii ni idi abajọ ti oun fi fakọyọ ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Everton.

Liverpool to wa nipo keji bayii gbọdọ jawe olubori nigba ti wọn koju Manchester United lọjọ Aiku ki wọn to le goke pada.