Gbogbo ìdíje ló ni ẹ̀kọ́ àti àwòkọ́ṣe to yẹ ni mímọ̀ fún ọjọ́ iwájú

Xherdan Shaqiri

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Xherdan Shaqiri ń dunú bọ́ọ̀lù tó gbá s'áwọ̀n

Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Liverpool ti gbo ewúro s'ójú Manchester United pẹ̀lú àmì ayò mẹ́ta sọ́kan (3-1) ní pápá ìṣeré Anfield.

Xherdan Shaqiri ló bá Liverpool jẹ bọ́ọ̀lù méjì ní ìṣẹ́jú mẹ́tàléàádọ́rin (73) àti ọgọ́rin (80) ìṣẹ́jú sí ìgbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ eré.

Agbábọ́ọ̀lù Liverpool Sadio Mané ló kọ́kọ́ gbá bọ́ọ̀lù sínú àwọ̀n nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ìdíje Premier League tí wọ́n gbá lajọ́ Àìkú.

Bẹẹ naa ni Manchester City na Everton pẹlu ami ayo mẹta sọkan lọjọ Abamẹta.

Nigba ti Southampton na Arsenal pẹlu ami ayo mẹta si meji lati fidi Arsenal gbolẹ lọjọ Aiku.

Chelsea na Brighton mọle pẹlu ami ayo meji sọkan lọjọ Aiku.

Àkọlé fídíò,

Gbogbo ènìyàn ló wọ agbádá ikú, ẹni tó kàn lẹnìkan kò mọ̀

Ẹ̀kọ́ inú ìdíje náà

Kò sí ìgbà ti ikọ agbabọọlu meji to gbona bii Liverpool ati Manchester United a pade ti gbogbo eniyan kò ni mọ pe irin lo ko irin.

1) Gbiyanju lati tẹle ipinnu rẹ dopin. O hande pe lati ibẹrẹ idije naa ni Liverpool ti n sa gbogbo ipá wọn lai ṣaarẹ pe ki ipinnu gbigba ẹyẹ Premiere League lè ṣẹ.

Liverpool lo pupọ ninu anfaani ti wọn ri ninu idije naa bẹrẹ lati aṣiṣe pẹlu Alisson Becker.

Koda, Jose Mourinho gbà pé ikọ mejeeji gbá bọọlu naa nipa agbara wọn. ni eyi to fihan pe owo nina yatọ si mimọ iṣẹ bọọlu gbigba de ibi to yẹ pẹlu ipinnu.

Eden

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Eden Hazard ti ji giri si ipo tuntun to dimu ni Chelsea

2) Kò sí ẹni ti itan rẹ kò le yipada. Eyi ni pe ko sẹni to yẹ ko ro ara rẹ pin laye.

Gabriel Jesus ti ko ri bọọlu kankan gbá sáwọ̀n lati ọṣu mẹrin sẹyin dẹni to n jẹ goolu meji laarin iṣẹju mejidinlọgbọn ninu idije kan ṣoṣo!.

Eyi lo sun ipo ẹgbẹ rẹ siwaju sii lori àtẹ bayii.

3) Gbiyanju lati ṣe ohun to yẹ ti wọn ba fun ọ ni ipo airotẹlẹ. Eden Hazard ti Chelsea ni Maurizio Sarri gbà pé o tó gbangba sun lọyẹ pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ ni kete to ti sun siwaju yii.

Ẹkọ ibi yii ni pe, o ṣeeṣe ki wọn gbe ọ sipo airotẹlẹ, gbiyanju koo tara, koo sa ipa rẹ lati rii pe o ṣe ohun to yẹ ni ṣiṣe lasiko. Koda Hazard lo gba ẹlẹsẹ ayo fun oṣu kẹsan an ninu idije Premier League yii.

Jose Mourinho ati Jurgen Klopp

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ere bọọlu nla

4) Ibẹrẹ kii ṣe oniṣẹ. Arsenal jẹ ẹgbẹ agbabọọlu ti wọn ko fẹyin wọn gbole lati igba pipẹ sẹyin ṣugbọn nkan ti n yipada sidakeji bayii nigba ti Southampton ti

nà wọn bayii ninu idije. Ọrọ naa ti de ibi pe, Unai Emery ti kilọ fun wọn ki wọn lọ tunra mu ti wọn ba fẹ kopa ninu idije sáà to m bọ.

agabbọọlu

Oríṣun àwòrán, @arsenal

Àkọlé àwòrán,

Odo ti a ba foju rénà le gbe eniyan lọ

5) Araba tunra mu, odo n gbe arere lọ ati pe ọpọ igba lo jẹ pé Igi ti a foju rénà a maa gbe ni ṣubu. Arsenal ti ẹru wọn n ba gbogbo ikọ agbabọọlu tẹle lo wa jẹ pe Souuthampton ti wọn gba pe ko jamọ nkankan pupọ lo wa na wa pẹlu ami ayo mẹta si meji. Wọn foju rénà Southampton, oun lo dẹ ba akọsilẹ wọn jẹ bayii.

Eric

Oríṣun àwòrán, @tottenham

Àkọlé àwòrán,

Adura ara lile laip#e ni op#o n gb[a fun Eric

6) Ko sẹni ti ìgbà rẹ ko le de nitori bi teeyan kan ko bajẹ, tẹlomii ko le daa nigbagbọ awọn Yoruba. Oliver skipp ọmọ ọdun mejidinlogun agbabọọlu Tottenham lo di ọkan lara aayo ori papa lataari Eric Dier to n gba itọju nile iwosan fun iṣẹ abẹ to ṣe. Pochettino to jẹ ọga wọn gboriyin fun Skipp pe o fakọyọ bo ti yẹ.

Idije Man U ati Liverpool

Lẹ́yìn náà ni Jesse Lingard bá Manchester United gbá bọ́ọ̀lù sí àwọ̀n Liverpool ní ìṣẹ́jú mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) sí ìgbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ eré.

mane

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Mané gbá bọ́ọ̀lù náà wọlé ní ìsẹ́jú mẹ́rìnlélógún sí ìgbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ eré

Ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ idije Premier League laarin Liverpool ati Manchester United nirọlẹ ọjọ Aiku, akọnimọọgba Liverpool Jurgen Klopp ni oun fẹ ki awọn agbabọọlu ikọ Liverpool fi'binu gba bọọlu pẹlu Man U ni.

Klopp ni ikanra ni Man United yoo gbe wa lẹyin ti Valencia fẹyin wọn gbolẹ ninu idije Champions League laarin ọṣẹ to kọja.

Jesse Lingard ló bá Manchester United gbá bọ́ọ̀lù sí àwọ̀n Liverpool

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Jesse Lingard ló bá Manchester United gbá bọ́ọ̀lù sí àwọ̀n Liverpool

Ṣugbọn akọnimọọgba Liverpool ni gudugudu awọn agbabọọlu oun naa ko fi gba kan tura silẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Man United ko tii na Liverpool mọle fun ọdun marun un sẹyin bayii.

Ẹwẹ, akọnimọọgba Man U Jose Mourinho sọ pe nnkan n ṣẹnu 're fun Liverpool lọwọ bayii nitori oke ti wọn wa ninu idije Premier League.

Mourinho sọ pe Liverpool ni igboya lati koju Man U nitori wọn jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta ti wọn gba sẹyin.

Klopp ko na ẹgbẹ ẹgbẹ agbabọọlu ti Mourinho n dari gẹgẹ bi akọnimọọgba ri.

Àkọlé fídíò,

''Ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣì n sọnù ni orilẹ̀-ede Burundi'