Champions League: Liverpool àti Bayern yóò gbéná wojú ara wọn

Mohamed Salah Image copyright Champions League
Àkọlé àwòrán Idije Champions League

Ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool ati Bayern Munich ni yoo koju ara wọn ni ipele ẹlẹnimẹrindinlogun(Round of 16) ninu idije UEFA Champions League saa ọdun 2018/2019.

Iroyin yi jẹyọ lẹyin ti wọn pari aṣayọ ọrukọ awọn ẹgbẹ agbabọọlu ti yoo kopa ninu abala ẹlẹnimẹrindinlogun ohun ni itẹsiwaju idije naa.

Ẹwẹ ikọ Manchester United yoo waako pẹlu Paris St-Germain lati orilẹede Faranse ninu ifẹsẹwọnsẹ miran ti yoo yọ eruku lala.

Manchester City ti wọn da bi ẹdun rọ bi owe lorileede Gẹẹsi ati Schalke ti ilẹ Germany naa wa lara awọn ifẹsẹwọnsẹ ti awọn ololufẹ ere bọọlu n foju sọna si.

Lalai ti koju ara wọn, awọn eeyan kan paapa julọ alatilẹyin Man City ti foju si pe Man City ni yoo gbegba oroke ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹgbẹ agbabọọlu Ilẹ Gẹẹsi miran Tottenham yoo ta kangbọn pẹlu Borussia Dortmund ti orilẹede Germany.

Ninu awọn ere bọọlu miran ni ipele yii, Atletico Madrid yoo koju Juventus, nigba ti Barcelona yoo maa figa gbaga pẹlu Barcelona.

Image copyright Champions League
Àkọlé àwòrán Odu ni Ronaldo jẹ,kii ṣe aimọ fun oloko Antoine Griezman ti ẹgbẹ agbabọọlu Atletico Madrid

Roma yoo gbena woju FC Porto, nigba ti Ajax yoo wọ ṣokoto kannaa pẹlu Real Madrid ti ife ẹyẹ naa wa lọwọ wọn.

Ọjọ kejila oṣu keji ọdun 2019 ni awọn ifẹsẹwọnsẹ ọhun yoo bẹrẹ.