Raiola bá Juventus sọ̀rọ̀ lórí ìpadàbọ̀ Pogba

Jose ati Paul Pogba
Àkọlé àwòrán,

Mino Raiola ati Juve a yanju ibi ti Paul Pogba a pada si

O ṣeeṣe ki agbabọọlu aarin gbungbun, Paul Pogba fi Manchester United silẹ lọ Juventus to ti wa tabi ki ikọ agbabọọlu miran raa lẹyin ti aṣoju rẹ, Mino Raiola, ṣepade pẹlu Juve lọjọ Aje.

Ṣugbọn ikọ Man U ko fẹ ki Pogba fi ẹgbẹ agbabọọlu naa silẹ lakoko yii.

Nkan ko fara rọ laarin Pogba ati akọnimọọgba Man United Jose Mourinho lati ibẹrẹ saa ere bọọlu yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Koda, Pogba ko si lara awọn agbabọọlu to ṣoju Man U ninu ifẹsẹwọnsẹ awọn ati Liverpool ti wọn ti fidi rẹmi.

Àkọlé àwòrán,

Mino Raiola lori ago

Iroyin sọ pe aṣoju Pogba, Raiola tun ti ba awọn ẹgbẹ agbabọọlu mii ti wọn nifẹ ki Pogba di agbabọọlu wọn sọrọ.

Pọgba tiẹ tun fi fọto to ya pẹlu akẹgbẹ rẹ tẹlẹ nigba to wa ni Juventus, Paulo Dybala lede loju opo Instagram rẹ lọjọ Aje.

Àkọlé àwòrán,

Paul Pogba ati akẹgbẹ rẹ tẹlẹ ni Juventus

Eyi lojẹ ki ọpọ ololufẹ ikọ Juve maa sọ pe ki o pada si Juventus to ti kuro.

Miliọnu mọkandinlaadọrin pọn-un(£89m) ni Juventus ta Pogba fun ikọ Man U lọdun 2016.