Jose Mourinho: Iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ akọ́nimọ̀ọ́gbá Man United

Jose Mourinho Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Jose Mourinho fi Manchester United silẹ

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo sọ pe iṣẹ ti bọ lọwọ akọnimọọgba ikọ Manchester United Jose Mourinho.

Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United lo fọrọ naa lede loju opo Twitter wọn.

Ọdun meji ati aabọ ni Mourinho fi tukọ ẹgbẹ agbabọọlu Man U ko to gbawe gbele ẹ lọjọ Iṣẹgun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Akọnimọọgba fidihẹ ni yoo dari ikọ agbabọọlu naa titi di ipari saa bọọlu yii, lẹyin naa ni awọn alaṣẹ ikọ Man U yoo ṣe ifọrọwanilẹnuwo lati gba akọnimọọgba tuntun.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ta ni yoo jẹ akọn

Ẹgbẹ agbabọọlu naa ki Mourinho fun iṣẹ to ṣe nigba ti o fi ṣe olukọni Manchester United.

Mourinho to jẹ ọmọ ọdun marunlelaadọta ami ẹyẹ League Cup ati Europa nigba to fi tukọ Manchester United.