Man City àti Chelsea jìyà nínú ìdíje ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

Palace

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Crytsal Palace ti sán bàǹtẹ́ ìyà fún Manchester City pẹlú àmì ayò mẹ́ta sí méjì.

Ẹ léyìí wáyé l'ọ́jọ́ Àbámẹ́ta nígbà tí Leicester City gbo ewúro sí ojúu Chelsea pẹ̀lú àmì ayò kan sí òdo.

Saájú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Arsenal ti kọ́kọ́ na Burnley pẹ̀lú àmì ayò mẹ́ta sí ọ̀kan nígbà tí Aubamenyang bá ẹgbẹ́ náà gbá bọ́ọ̀lù méjì s'áwọ̀n Burnley.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Michael Obafemi bá Southamton gbá bọ́ọ̀lù sí àwọ̀n nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn pẹ̀lú Huddersfield

Ẹléyìí jẹ́ kí Aubameyang jẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó jẹ bọ́ọ̀lù jù nínú ìdíje náà lọ́wọ́-lọ́wọ́ .

Ta ni Michael Obafemi?

Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Southampton f'agbà han Huddersfield pẹ̀lú àmì ayò mẹ́ta sí ọ̀kan níbi tí Michael Obafemi ti gbá bọ́ọ̀lù kan sí àwọ̀n.

Ọmọ Nàìjíríà ni àwọn òbí Michael Obafemi. Ṣùgbọ́n wọ́n bí agbábọ́ọ̀lù náà sí ilú Dublin ní ilẹ̀ Ireland ni ní ọdún 2000.

Àmọ́sá ilú London ni Michael dàgbà sí. Ní ọdún 2016 ló darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ Southampton. Ní ọjọ́ kọọ̀kànlélógún (21) oṣù kíní ọdún 2018 ni Michael bẹ̀rẹ̀ sí bá Southamton gbá bọ́ọ̀lú níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn pẹ̀lú Tottenham Hotspur.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Jamie Vardy ló jẹ bọ́ọ̀lù tó ṣe Chelsea bi ọsẹ ṣeé ṣe ojú

L'ọ́jọ́ Àbámẹ́ta ló di agbábọ́ọ̀lù tó kéré jù lọ́jọ́ orí tó bá Southamton jẹ bọ́ọ̀lù nínú ìdíje líígì ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

Bákan náà Watford na West Ham pẹ̀lú àmì ayò méjì sí òdo nígbà tí Bournemouth náà Brighton pẹ̀lú àmì ayò méjì sí òdo.