Eégún Iwobi jóo re, orí ya Liverpool

iwobi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ori n ya atọkun Iwobi

Unai Emery ti gboriyin fun Alex iwobi ati Maitland-Niles.

Lọjọ Abamẹta ni Liverpool gbo ewuro soju Arsenal ti wọn na wọn pẹlu ami ayo marun un sookan ni papa iṣere Anfield.

Akọnimọọgba Arsenal yii yombọ iṣẹ akọni to gba pe Iwobi ṣe ninu idije naa nibi ti o ti fun Nile ni bọọlu to gba sawọn niṣẹju kọkanla ti idije naa bẹrẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ti irin ba kan irin, ọkan a tẹ fun ikeji

Ere ni ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal kọkọ pe idije naa titi ti Sadio Mane fi gba a fun Mohammed Salah ni eyi ti wọn fi sọọ di ami ayo mẹta sookan labala saa akọkọ idije naa.

Firmino lo tun sọ ọ sawọn fun wọn niṣẹju marundinlaadọrin pẹlu kọju-simi-o gbaa sile.

Àkọlé fídíò,

Asisat Oshoala: ìbẹ̀rẹ̀ mi kò rọrùn rárá nínú eré bọ́ọ̀lù

Loju akọnimọọgba Emery, Iwobi gbiyanju ninu idije naa fun odindin iṣẹju aadọrun un idije ọhun.

Eyi ni idije kẹta sẹyin ti ẹgbẹ agbaọọlu Arsenal ti fidirẹmi sẹyin ni eyi ti akọnimọọgba wọn ni o fihan pe iṣẹ pọ niwaju wọn lati ṣe ni.

Àkọlé fídíò,

Èpo ọwọn, sunkere-fakere ọkọ àti àwọn olósà jẹ́ ipenija lójú pópó

Ọrọ loriṣiiriṣii làwọn ololufẹ BBC Yorùbá ti wọn da si ọrọ idije naa fi lede.

Bi awọn kan ti n fi Arsenal ṣe yẹyẹ lori ayelujara ni awọn mii gab pe ojoojumọ kọ lọdun ni idije naa jẹ.

Àkọlé àwòrán,

aju ara wa lọ, ijakadi kọ

Bẹẹ, ko si eegun ti yoo joo re ti atọkun rẹ ko ni ṣai fidunnu han ni ọrọ awọn ololufẹ Liverpool lori ikanni BBC Yoruba pe:

Àkọlé àwòrán,

Igba iponju lawọn aladuroti n rẹ ni

Bẹẹ lawọn mii gba pé o dabi pe papa iṣerẹ naa kii ṣe fun Arsenal lasiko idije naa ni

Àkọlé fídíò,

Saba Gul: Ọmọbìnrin aláìlápa tí o fẹ̀ dì agbẹjọro