Emiliano Sala: 'Kò sí ìrètí pé wọn yóò rí agbábọ́ọ̀lù Cardiff City tó sọnù'

Emiliano Sala Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Emiliano Sala n pada si Cardiff lọjọ Aje lẹyin to buwọlu iwe adehun iṣẹ tuntun, lo kagbako iṣẹlẹ naa

Ko ti i si ireti tabi idaniloju pe wọn yoo ri agbabọọlu Cardiff City, Emiliano Sala, ọkan lara awọn addola ẹmi lo sọ bẹ.

Ọmọ orilẹede Argentina ọhun, to jẹ ẹni ọdun mejidinlọgbọn, ati awakọ ofurufu kan lo jọ wa ninu ọkọ baalu naa to deede poora ni erekusu Channel lalẹ ọjọ Aje.

Ọga agba fun ṣiṣe awari loju ofurufu ni Erekusu Channel, John Fitzgerald, sọ pe ''ẹni ti ara a rẹ pe julọ'' ko le lo ju wakati diẹ lọ ninu omi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMurphy Elégungun Rọba: Mo fẹ́ di ẹnití egungun rẹ rọ jùlọ ní àgbáyé

Awọn adoola ẹmi tun ti pada bẹrẹ si ni wa ọkọ oju ofurufu naa to poora ati awọn to wa ninu rẹ, lọjọru.

Iroyin kan sọ pe Sala fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si awọn mọlẹbi rẹ lori ẹrọ ayeluja Whatsapp, pe ''ẹru ba oun pupọ.''

Awọn ileeṣẹ iroyin l'orilẹede Argentina jabọ iroyin pe Sala sọ fun mọlẹbi rẹ pe ''Mo wa ninu ọkọ ofurufu kan to dabi ẹni pe o fẹ ẹ jabọ.''

Image copyright Ben Birchall/PA WIRE
Àkọlé àwòrán Awọn eniyan ti gbe òdòdó àti ọrọ iwunilori silẹ ni ita paapa iṣere Cardiff

Ni nkan bi aago mọkanla aabọ owurọ l'Ọjọru, ileeṣẹ ọlọpaa ni Guernsey sọ pe ọkọ ofurufu mẹta ati baalu kekere kan wa loju ofurufu, bi wọn ṣe n wa baalu Piper Malibu.

Bakan naa ni awọn ọlọpaa sọ pe 'awọn ti n ṣayẹwo akọsilẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ lati mọ boya iranlọwọ kankan le ti ibẹ jade. Ṣugbọn titi di asiko yii, ko ti i si iroyin kankan nipa baalu to poora naa.

Olu ilu orilẹede Welsh ni Sala n lọ lẹyin to buwọlu iwe adehun iṣẹ miliọnu mẹẹdogun Pọun pẹlu ikọ Bluebirds.