Chelsea: Sarri ní Eden Hazard lè lọ tó bá fẹ́ lọ

Maurizio Sarri ati Eden Hazard Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọrọ lori ẹlẹsẹ ayo Eden Hazard

Akọnimọọgba Chelsea Maurizio Sarri ti sọ fun ẹlẹsẹ ayo Eden Hazard pe o le fi ẹgbẹ agbabọọlu naa silẹ to ba wu u.

Sarri ni lootọ l'oun fẹ ki Hazard duro ni Chelsea, ṣugbọn oun ko ni di i lọna ti o ba fẹ fi ikọ agbabọọlu naa silẹ.

Iroyin ti n gbe e jade tipẹ pe ikọ Real Madrid fẹ ki Hazard darapọ mọ ikọ ọhun lorilẹede Spain.

Ọsẹ tó nira julọ fún mi rèé- Neil Warnock

Ìyá lu ọmọ rẹ̀ pa nítorí 21,000 Naira

Aṣòfin ọmọ Naijiria ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì rẹ́wọ̀n oṣù mẹ́ta he

Bakan naa ni Hazard fun ra rẹ ti sọ pe o wu oun lati darapọ mọ ikọ Real Madrid to jẹ pe awọn ni ife ẹyẹ UEFA Champions League wa lọwọ wọn bayii.

Ikọ Chelsea fẹ ki Hazard bọwọ lu iwe adehun tuntun ki o to di pe adehun to wa laarin wọn yii yoo tan lọdun to n bọ.

Hazard to darapọ mọ Chelsea lọdun 2012 ti gba ayo mẹwaa sawọn fun Chelsea ninu idije Premier League ti saa yii.