Ere Idaraya: Aáwọ̀ ààrin Wenger àti Mourinho ti parí

Akọnimọọgba Arsenal nigba kan ri Arsene Wenger kọ lu akọnimọọgba Chelsea nigba kan ri Jose Mourinho

Oríṣun àwòrán, Shaun Botterill

Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọlu Arsenal nigba kan ri, Arsene Wenger gbami ẹyẹ Laureus ni ọjọ Aje, ṣugbọn ohun to yani lẹnu ju ni ẹni to gbori yin fun, tii se Jose Mourinho

Wenger, ẹni ọdun mọkandinlaadorin gba ami ẹyẹ naa nitori ipa to ko lori bọọlu afẹsẹgba ni Ilẹ Gẹẹsi, ni paapaa, fun ọpọlọpọ ọdun to lo gẹgẹ bii olootu ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal.

Ọpọlọpọ igba si ni Wenger ati Mourinho maa n kọlu ara wọn lori papa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

'Arsene Wenger gbọdọ lọ'

Ṣugbọn, Mourinho ti Manchester United le lọ ile ni oṣu Kejila ọdun 2018, ti buyi kun Wenger ninu fidio kan.

Ọmọ orilẹede Portugal naa, to tukọ Chelsea fun saa meji ko to tukọ Man U fun saa kan, ni lootọ ni wipe, awọn kọlu ara wọn nigba ti wọn jọ wa lẹnu iṣẹ.

Ọrọ naa tilẹ buru to bẹẹ nigba kan ti Wenger ti Mourinho lulẹ lori papa nitori pe Mourinho sọ ọrọ alufansa si.

Mourinho sọ ninu fidio naa wipe, ọpọlọpọ oun lo ṣẹlẹ nigba yẹn lọun. O ni, "Mo fẹran bi a ṣe maa n fi iga gbaga, ṣugbọn mo buyi kun pupọ. Wenger sa ipa ribiribi ni ẹgbẹ agbabọọlu naa. O wa lara akọnimọọgba to dara ju ninu itan Arsenall

Wenger ni ọrọ Mourinho naa ya oun lẹnu pupọ nigba to gba ami ẹyẹ naa. O ni inu oun dun wipe wọn yẹ oun si gẹgẹ bii akọnimọọgba.