EPL: Brendan Rodgers ni akọ́nimọ̀ọ́gbá tuntun fún Leicester City

Brendan Rodgers

Oríṣun àwòrán, Twitter/Leicester City

Àkọlé àwòrán,

Brendan Rodgers darapọ mọ Leicester

Akọnimọọgba Liverpool tẹlẹri, Brendan Rodgers ni wọn ti yan gẹgẹ bi akọnọmọọgba Leicester City bayii.

Rodgers fi Celtic silẹ lati rọpo Claude Puel ti ẹgbẹ agbabọọlu naa da duro lẹnu iṣẹ lọjọ Aiku lẹyin to lo ọdun kan ati oṣu mẹrin lẹnu iṣẹ.

Rodgers ti fọwọ si iwe adehun lati jẹ akọnimọọgba ikọ Leicester di ọdun 2022.

Iṣẹ tuntun ti Rodgers gba yii yoo mu pada si idije Premier League lẹyin to ti jẹ akọnimọọgba Liverpool ati Swansea City ri tẹlẹ.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Leicester

Àkọlé àwòrán,

Brendan Rodgers buwọ luwe

Ninu ọrọ rẹ, Rodgers ni oun yoo lo gbogbo aye oun lati ri wi pe inu awọn ololufẹ Leicester City dun.

Ẹwẹ, adile mu fun Arsenal ati Manchester City tẹlẹ, Kolo Toure naa ti darapọ mọ Leicester gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ Rodgers.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Brendan Rodgers darapọ mọ Leicester City

Toure ba Rodgers ṣiṣẹ nigba to wa pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Celtic lorilẹede Scotland.