Champions League Draw: Barcelona yóò kojú Man U ní ìpele 'quarter finals'

Ami Man U ati Barcelona Image copyright Twitter/Manchester UNited
Àkọlé àwòrán Idije Champions League

Eegun kan eegun lọrọ ifẹsẹwọnsẹ ipele kọmẹsẹọyọ ẹlẹni mẹjọ(quarter finals) idije UEFA Champions League lẹyin ti wọn gbe Barcelona koju Manchester United.

Image copyright Twitter/Pogba
Àkọlé àwòrán Idije Champions League

Ifẹsẹwọnsẹ lọpọlọpọ ololufẹ ere bọọlu sọ pe o le julọ ninu gbogbo rẹ.

Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City naa yoo maa waako pẹlu Tottenham Hotspur ninu ifẹsẹwọnsẹ miran.

Ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ Gẹẹsi lawọn ikọ agbabọọlu mejeeji ti wọn si ti koju ara wọn ninu idije Premier League ni saa yii.

Ikọ Liverpool to de ipele aṣekagba idije UEFA Champions League ni saa to lọ yoo maa ta kangbọn pẹlu ikọ FC Porto.

Ajax to le Real Madrid ti ife ẹyẹ naa wa lọwọ lọ le yoo maa gbalejo Juventus, ẹgbẹ agbabọọlu Cristiano Ronaldo.