FA Cup: Man City pòkọ ìyà fún Swansea pẹ̀lú àmì ayò 3-2 nínu FA Cup

KUn Aguero Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Idije FA Cup

Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ti pgede fun ipele to kangun si aṣekagba ninu idije FA lẹyin ti wọn fagba han Swansea City pẹlu ami ayp 3-2.

Swansea lo kọkọ gbayo meji wọ le ami ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun.

Matt Grimes lo akọkọ naa wọle nibi ogun iṣẹju ti wọn bẹrẹ ere bọọlu ọhun.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Idije FA Cup

Agbabọọlu Manchester City lo gbe ọkan ninu awọn agbabọọlu Swansea ṣubu, ti rẹfiri si fun wọn ni pẹnariti.

Bersant Celina lo gbayo keji wọle fun Swansea.

Ṣugbọn Man City ji pada ninu ere bọọlu ọhun eleyi to mu ki Bernardo Silva dayo kan pada.

Kun Aguero ti akọnimọọgba Pep Guardiola gbe wọ gba pẹnariti ṣugbọn ẹsẹ goli lo gba bọọlu sawọn lo ba di ọmi 2-2.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán FA Cup

Aguero tun ṣe bẹẹ lo ba tun gbayo wọ le fun Man City eleyi to mu wọn jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Idije FA Cup