AFCON 2019: Amuneke gbé Tanzania lọ ìdíje ilẹ̀ Afirika fún'gbà àkọ́kọ́ láti ọdun 1980

Emmanuel Amunake Image copyright Twitter/Emmanuel Amuneke
Àkọlé àwòrán AFOCN 2019

Orukọ akọnimọọgba Emmanuel Amuneke ti wọ iwe itan lẹyin to ṣagbatẹru bi orilẹede Tanzania ti pegede fun idije ere bọọlu ilẹ Afirika-AFCON fun igba akọkọ ni nnkan bi ọdun mọkandinlogoji(39 years).

Ikọ Taifa Stars orilẹede Tanzania ti agbabọọlu Naijiria tẹlẹ, Amuneke jẹ akọnimọọgba wọn pegede lati kopa ninu idije AFCON 2019 lẹyin ti wọn pokọ iya fun Uganda pẹlu ami ayo mẹta sodo lọjọ Aiku.

Simon Msuwa, Erasto Nyoni ati Aggrey Morris lo gba bọọlu sawọn ti Tanzania fi dero AFCON 2019.

Ikọ agbabọọlu Amuneke lo ṣepo keji ni isọri 'L' ti ẹgbẹ agbabọọlu Cranes of Uganda si ṣe ipo kinni.

Tanzania ati Uganda ti darapọ mọ orilẹede Egypt to n gbalejo idije naa, Nigeria,Burundi, Mali, Cameroon, Morocco, Angola, Mauritania, Senegal, Madagascar, Algeria, Benin, Ghana, Kenya, Zimbabwe, Congo, Guinea, Ivory Coast, Tunisia, Guinea-Bissau ati Namibia gẹgẹ bi awọn ikọ ti yoo kopa ninu idije AFCON 2019.

Igba akọkọ ree ti idije AFCON yoo waye ninu oṣu kẹfa si ikeje, bakan naa ikọ agbabọọlu mejilelelogun yoo kopa fun igba akọkọ dipo mẹrindinlogun to ti wa tẹlẹ.