AFCON: Amuneke lọmọ Nàìjíríà kejì tó gbé orílẹ́èdè míì lọ sí ìdíje ilẹ̀ Afirika

Stephen Keshi pẹlu Emmanuel Amuneke Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn agbabọọlu Naijiria

Akọnimọọgba Emmanuel Amuneke ti di ọmọ orilẹede Naijiria keji to ṣagbatẹru bi ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ okere ti pegede fun idije AFCON.

Orukọ Amuneke wọ iwe itan lẹyin to ṣagbatẹru bi orilẹede Tanzania ti pegede fun idije ere bọọlu ilẹ Afirika- AFCON 2019 fun igba akọkọ ni nnkan bi ọdun mọkandinlogoji(39 years).

Image copyright Twitter/Emmanuel Amuneke
Àkọlé àwòrán Emmanuel Amuneke fakọyọ nilẹ okere

Ikọ Taifa Stars orilẹede Tanzania ti agbabọọlu Naijiria tẹlẹ, Amuneke jẹ akọnimọọgba wọn pegede lati kopa ninu idije AFCON 2019 ti yoo waye lorilẹede Egypt lẹyin ti wọn pokọ iya fun Uganda pẹlu ami ayo mẹta sodo lọjọ Aiku.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÈré Ọṣun: Àtáója ní wọn kò jí ère Ọṣun, ó sì wà níbi tó wà

Ikọ agbabọọlu Amuneke lo ṣepo keji ni isọri 'L' ti ẹgbẹ agbabọọlu Cranes of Uganda si ṣe ipo kinni.

Image copyright Instagram/Emmanuel Amuneke
Àkọlé àwòrán AFCON 2019

Ṣaaju akoko yii, oloogbe Stephen Keshi lo gbe ikọ agbabọọlu Togo lọ si idije AFCON lọdun 2006.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn agbabọọlu Naijiria

Bakan naa, oloogbe Keshi ni akọnimọọgba orilẹede Togo nigba ti wọn pegede fun ife ẹyẹ agbaye fun igba akọkọ eyun ni 2006 FIFA World Cup ti orilẹede Germany gbalejo rẹ, bi o tilẹ jẹ pe wọn gbaṣẹ lọwọ rẹ ki idije naa to bẹrẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ere bọọlu ilẹ Afirika

Keshi ti orukọ inangijẹ rẹ jẹ ''Big Boss'' lagbo ere bọọlu ni Naijiria naa lo tun ko ẹgbẹ agbabọọlu Mali lọ si idije AFCON lọdun 2010.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Idije AFCON ọdun 2010

Lẹyin ti wọn da Keshi duro gẹgẹ bi akọnimọọgba ikọ agbabọọlu Mali lo di akọnimọọgba fun ikọ Super Eagles ti orilẹede Naijiria.

Keshi lo gba ife ẹyẹ AFCON ti ikọ Naijiria gba kẹyin lọdun 2013 lorilẹede South Africa.