#AFCONU23Q: Nàìjíríà na Libya lálùdákú pẹ̀lú àmì ayò 4-0

Victor Osimhen ati awọn akẹgbẹ rẹ Image copyright Twitter/NFF
Àkọlé àwòrán #AFCONU23Q

Alubami ni ikọ agbabọọlu U23 Naijiria lu akẹgbẹ wọn Libya lati pegede fun ipele to kẹyin si idije AFCONU23

Goolu mẹta ọtọtọ ni ẹlẹsẹ ayo Victor Osimhen nikan gba sawọn Libya ti Naijiria si fagba han akẹgbẹ wọn pẹlu àmì ayò mẹ́rin sodo(4-0).

David Okereke lo fọba lee, lẹyin to gba goolu ẹlẹẹkẹrin wọle Libya, bẹẹ lawọn ọmọ Naijiria fijo bẹẹ nilu Asaba ti ere bọọlu ọhun ti waye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÈré Ọṣun: Àtáója ní wọn kò jí ère Ọṣun, ó sì wà níbi tó wà

Libya lo jawe olubori pẹlu ami ayo meji sodo ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ti wọn gba lorilẹede Libya lọsẹ to kọja.

Ṣugbọn ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria fakọyọ ni papa iṣere Stephen Keshi lọjọ Aje lẹyin ti wọn gbayo mẹrin sawọn ti Libya kosi le da ẹyọkan pada.

Nibayii orilẹede Sudan tabi Kenya ni ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria yoo koju bayii ninu ipele to kan.

Orilẹede Egypt ni yoo gbalejo idije ọhun to jẹ ẹlẹkẹẹta iru rẹ, ninu oṣu kọkanla ọdun yii.