Premier League: Liverpool na Tottenham láti gòkè tábìlì EPL

Liverpool fakọyọ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Liverpool na Tottenham

Oni lonii jẹ, ẹni a bẹ lọwẹ, ọjọ irọlẹ ọjọ Aiku yii ni ikọ Liverpoool yoo ta kangbọn pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham ninu idije Premier League.

Ọpọ ololufẹ ere bọọlu papaa julọ awọn to n tele idije Premier Legaue sọ pe ifẹsẹwọnsẹ ọhun yoo yeruku lala nitori Liverpool fẹ gba ami ẹyẹ naa ni saa yii.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Idije Premier League

Ọdun kọkandinlọgbọn ree ti ikọ Liverpool ti gba ife ẹyẹ ere Ilẹ Gẹẹsi kẹyin, ipo keji ni wọn si wa bayii lori tabili idije Premier League nigba ti Manchester City wa loke tente.

Ẹwẹ, ẹlẹsẹ-ayo fun ikọ Liverpool Mohamed Salah kuna lati gba bọọlu sawọn ninu ifẹsẹwọnsẹ meje to gba sẹyin.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Liverpool gbalejo Tottenham
Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Liverpool gbalejo Tottenham

Ṣugbọn akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool Jurgen Klopp sọ pe isinmi ranpẹ ti Salah ni nigba to lọ soju orilẹede Egypt yoo ṣeranwo fun un to ba dee.

Ipo kẹta ni ikọ Tottenham wa lori tabili Premier League, ami ayo kan si ni wọn fi siwaju Manchester United to wa ni ipo kẹrin.

Aago mẹrin aabọ ni ifẹsẹwọnsẹ yoo bẹrẹ ni papa iṣere Liverpool tii ṣe Anfield.