Champions League: Barca da yẹpẹ sí gaàrí Man U ní Old Trafford

Paul Pogba ati Suarez Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Champions League

Aileja lojude ile baba mi ko debi. Bẹẹ gẹgẹ lọrọ ikọ Barcelona ri lẹyin ti na Manchester United mọ le.

Adiẹyin mu Luke Shaw lo ṣeeṣi gba goolu sile ara rẹ, eleyi to mu ki Barca jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán UEFA Champions League

Adile mu fun ikọ Man U, Chris Smalling ti kọkọ fi igboya sọrọ pe ko si ohun ti ẹlẹsẹ ayo ati ageni bi ẹni layin, Lionel Messi yoo ṣe bi o tilẹ jẹ wi pe akọnimọọgba Man U, Ole Gunnar Solskjaer ni yoo ṣoro diẹ lati mu Messi.

Messi ti gba goolu mẹtalelogoji sawọn ni saa ere bọọlu yii ni kan, eleyi to si tun jẹ ki awọn akẹgbẹ rẹ bẹru rẹ kaakiri ilẹ Yuropu.

Ṣugbọn Smalling ni ikọ Man U ti koju awọn agbaọjẹ agbabọọlu ni Cristiano Ronaldo ati Kylian Mbappe, o ni Messi naa ko ni yatọ si wọn.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Champions League: Messi yóò kojú Man U nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tí yóò ta lẹ́nu

Akọnimọọgba Solskjaer ni Messi nikan kọ ni Man U yoo koju nitori awọn agbabọọlu mii bii Luis Suarez, Philippe Coutinho, Ivan Rakitic ati Arturo Vidal wa ni Barca.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Champions League: Messi yóò kojú Man U nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tí yóò ta lẹ́nu
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionHakeem: Mo lè sọ arúgbó dí ọmọge nígbà tó bá wù mí

Ninu ifẹsẹwọnsẹ keji to waye, ọmi alayo kọọkan ni Ajax ati Juventus ta.

Cristiano Ronaldo lo kọkọ fori gbe bọọlu wọ le Ajax ki Ajax to dayo naa pada.

Ipele keji ifẹwọnsẹ mejeeji yoo waye lọsẹ to mbọ.

Eleyi lo maa sọ ikọ agbabọọlu ti yoo pegede fun ipele to kangun si aṣekagba.

Ajax naa ko ṣe foju di nitori awọn lo ran Real Madrid ti ife ẹyẹ Champions League wa lọwọ rẹ lọ sile.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionParental Guidance: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀