UEFA Champions League: Ó di gbéré! Messi ṣekú pa Man United pẹ̀lu 3-0

Lionel Messi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Idije UEFA Champions League

Ajẹtun iya ni ikọ Manchester United jẹ lọwọ Barcelona ninu idije UEFA Champions League.

Elegee ara Lionel Messi lo fimu Man U danrin lẹyin to gba goolu meji sawọn labala akọkọkọ ifẹsẹwọnsẹ ọhun ni papa isẹre Nou Camp.

Adilemu fun Man U Ashley Young lo gba bọọlu lẹsẹ rẹ lẹyin naa lo tun ge agbabọọlu Man U meji mii ko to gbayo naa sawọn.

Messi yẹyẹ aṣọle Man U fun goolu ẹlẹẹkeji to gba wọ le lẹyin ti David De Gea mu amubọ.

Phillipe Coutinho fi ọba le fun Barcelona lẹyin to gba goolu aramọnda wọ le eleyi to jẹ goolu kẹta ti Barca gba sawọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni bayii ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona yoo koju Liverpool tabi FC Porto ni ipele to kangun si aṣekagba idije Champions League

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Idije UEFA Champions League

Ninu ifẹsẹwọnsẹ keji to tun wa lalẹ oni bakan naa, Cristiano Ronaldo gba goolu wọ le fun ikọ Juventus.

Ọmi ni wọn ta ni ipele akọkọ ere bọọlu ọhun nitori ẹgbẹ agbabọọlu Ajax dayo ti Ronaldo gba wọ le pada.

Ronaldo ati Juventus fidi rẹmi nitori Ajax lo jawe olubori pẹlu ami ayo si ẹyọkan ni papa iṣere Juve.