Femi Falana: Ìjọba Buhari kò lé è dá ààbò bo àwọn ará ìlú

Femi Falana

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán,

Gbajúgbajà Agbẹjọ́rọ̀ Femi Falana ti ní àwọn olósèlú ló wá ní ìdí ìsekúpani àti ìjínigbé lórílẹ̀èdè Nàíjíríà.

Ajafẹtọ Ọmọniyan, Femi Falana ti bu ẹnu atẹ lu isejọba Aarẹ Buhari lori eto aabo to mẹhẹ lorilẹede Naijiria.

Femi Falana lori eto kan ni ile isẹ iroyin Channels Television ijọba to wa lode yii ti fihan gbangba pe wọn ko le e da abo bo awọn ọmọ Naijiria nitori ijinigbe ati ipaniyan n peleke si ni.

O fikun wi pe awọn oloselu lorilẹede Naijiria lo wa ni idi isekupani ati ijinigbe to n waye ni awọn ilu to wa ni orilẹede naa lẹyin idibo gbogboogbo to kọja.

Àkọlé fídíò,

'Èmi ò kí ń lu ìyàwó mi'

Bakan naa lo ni Ile Igbimọ Asofin n fi ọrọ aabo to kan awọn ara ilu falẹ, nitori wọn ni asẹ lati se awọn ofin ti yoo pese eto aabo to gboro fun awọn eniyan.

Ajafẹtọ ọmọniyan naa wa parọwa si awọn adari ni ile aarẹ ni Abuja ati Ile Asofin ni apaapọ lati ye e kun, amọ ki wọn wa wọrọkọ fi sada lori eto abo ara ilu.