Napoli vs Arsenal: Ìdùnú subú lu ayọ̀ lórí itẹsiwaju Arsenal nínú ìdíje Europa

Aworan Alexandre Lacazette to n dawọ idunnu pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ati agbagbọọlu ẹgbẹ Arsenal ati alatilẹyin wọn ni ẹrin gba ẹnu wọn

Bi eegun ni ba joo re, Yoruba ni niṣe ni ori a ma ya atọkun rẹ.

Eegun ikọ Arsenal to fagba han Napoli lati tẹsiwaju lọ abala to kangun si aṣekagba idije Europa Liigi lo mu ki awọn alatilẹyin ẹgbẹ agbabọọlu naa maa gara.

Toun ti akitiyan Napoli, goolu ti Alexander Lacazette jẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ naa lo la ija laarin awọn mejeeji ti Arsenal si fi pegede.

Awọn alatilẹyin ẹgbẹ Arsenal ko tilẹ jẹ ki o pẹ rara ti wọn fi bẹrẹ si ni yọnu eebu si awọn alatilẹyin Napoli lori ẹrọ ayelujara.

Ninu ọrọ ti rẹ Marwan Nawaz gboṣuba kare fun akọnimọọgba Arsenal Unai Emery fun ipa to ko ninu aṣeyọri naa

Alebu kan to kan wa ba aṣeyọri yii wa ni bi Aaron Ramsey ti ṣe fi ara pa ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun.

Ohun ti eleyii tunmọ si ni pe ko ni laanfaani lati gba bọọlu mọ ni saa ọdun yii.

Bi a ba ni ki a wo ọrọ Europa yii, odu ni akọnimọọgba Arsenal, Unai Emery. Akọsilẹ wa pe o ti pegede nigba mẹrindinlọgbọn labala komẹsẹoyo idije Europa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Lacazette lo jẹ goolu kan ṣoṣo ti Arsenal jẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ naa

Emery ti gba ife Europa lẹmẹẹta pẹlu Sevilla nigba to n dari wọn laarin ọdun 2013-2016.

Ifẹsẹwọnsẹ Arsenal pẹlu Napoli ni ifẹsẹwọnsẹ aadọta ti Emery yoo dari gẹgẹ bi adari ikọ naa.

Ni bayii, Arsenal yoo koju Valencia lọjọ keji oṣu Kaarun labala to kangun si aṣekagba idije Europa.