Premier League: Crystal Palace yẹ̀yẹ́ Arsenal bí Everton ṣe dígbájú ru Manchester U

Awọn agbabọọlu Arsenal

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Idije Premier League

Tẹni to de laari, a ko mọ tẹni to n bọ lọrọ awọn ifẹsẹwọnsẹ idije Premier League to waye lọjọ Aiku.

Lẹyin ti Everton pokọ iya fun Manchester United ni papa isẹre Goodison Park tan ni Crystal Palace ki Arsenal mọ lẹ nile wọn ti wọn si ki bẹndẹ siwọn ninu.

Ami ayo mẹta si meji ni Palace fi ṣagba fun awọn Gunners nile wọ.

Àkọlé fídíò,

Helen Paul sọ idi tó fi gba orúkọ ní kékere

Arsenal si wa ni ipo kẹrin lori tabili Premier League, ṣugbọn Chelsea yoo gba ipo naa mọ wọn lọwọ ti wọn ba jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ ti wọn lọjọ Aje.

Esi ere bọọlu yii jẹ iyalẹnu fun awọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal lẹyin ti wọn na Napoli tan ninu idijẹ Europa League.