Kàkà kílẹ̀ ó kú...Chelsea kọ́ láti fìyà panu bíi Arsenal àti Man U

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Goolu mẹrin laarin iṣẹju mẹẹdọgbọn ni Chelsea ati Burnley jẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ́ wọn lalẹ ọjọ aje.
Toun ti igbiyanju ikọ Mauricio Sarri, wọn ko ribi bori Burnley amọ wọn ti bọ si ipo kẹrin lori afara liigi bayi.
Oun gbogbo lori top 4 ni orin to ku ti ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea nkọ bayi amọ ki orin naa to le dun lẹnu wọno jọ pe wọn yoo ṣi yi duro diẹ si.
Ipade awọn at Burnley lalẹ ọjọ Aje jẹ eleyi ti ọ́pọ ro pe Chelsea yoo fi fẹsẹ rinlẹ lori ipo kẹrin ṣugbọn ko ri bẹ.
Chlesea ti wa ni ipo kẹrin lori afara liigi bayi pẹlu ami mẹ́tàdínláàdọ́rin Burnley si wa ni ipo kẹẹdogun pẹlu ami ogoji
Goolu Mẹrin labala kini
Abala ikini ifẹsẹwọnsẹ naa ko dẹrun rara.Ifẹsẹwọnṣẹ naa gbona ju ina lọ.
Laarin isẹju mẹrinlelogun,awọn ikọ mejeeji ti gba ayo meji meji wọ ile ara wọn.
Burnley lo kọkọ jẹ ki Chelsea to da pada.Ki a to diju ki ato la,Burnley ti fi ikeji si.
Amọ Chelsea gbọnranu ti wọn si jẹ goolu keji.Hudson Odoi farapa ti wọn si gbe jade ki Pedro to wọle fun.