Gómìnà Sanwo Olu ní òun kò sanwó ẹbùn N41.4m fagbábọ́ọ̀lù Super Eagles

Image copyright @jidesanwoolu
Àkọlé àwòrán Ẹ yé irọ́ pa, mí o fún Super Eagles ní ẹbùn owó kánkan -Sanwo Olu

''Orukọ Sanwo Olu maa n ta iroyin daadaa; amọ, lori eleyi ti wọn gbe wi pe mo san owo ẹbun fawọn Super Eagles, irọ pọnbele ni''

Idahun re e ti Gomina ipinlẹ Eko fọ lori ọrọ to n ja ranyin-ranyin pe o ta agbabọọlu kọọkan lara ikọ Super Eagles Naijiria lọrẹ ẹgbẹrun marun un dọla.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu igbakeji agbẹnusọ rẹ, ọgbẹni Gboyega Akosile, o ni Gomina Sanwo Olu lọ si Egypt lootọ amọ ko ṣadehun tabi fun awọn Super Eagles lowo kankan.

''Irọ patapata ni iwe iroyin gbe. Ko si nnkan to jọ pe Gomina ipinlẹ Eko fun awọn Super Eagles ni owo moriwu.''

''O jẹ iyalẹnu pe iru iwe iroyin nla bi Punch yoo gbe ahesọ iroyin bayi.''

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFulani Kidnapping: Owó púpọ̀ la san kí wọ́n tó fi mi sílẹ̀

Lẹyin ifẹsẹwọnsẹ ikọ agbabọọlu Super Eagles Naijiria ti wọn ti gbewuro soju Cameroon lati tẹsiwaju ninu idije Afcon 2019 ni iroyin naa bẹrẹ si nija pe Sanwoolu fun wọn lowo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYPP, ADC, PPC ni tòótọ́ ni pé ọmọ oninakuna nijọba Eko lasiko yii

Ọrọ yi mu iriwisi ọtọọtọ wa loju opo Twitter ti awọn kan si n bẹnu atẹ lu gomina pe ko na owo si ibi to yẹ

Ero otọọtọ ni ọrọ owo naa n bí

Koda awọn ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Eko, gẹgẹ bi ohun ti Akosile sọ, kun awọn to gbe iroyin ẹlẹjẹ yi.

''Owo ti awọn ti ẹ wa sọ gọbọi. Wọn ni $470m ni Gomina na lati gbe ara rẹ ati awọn ọmọ ẹgbẹ APC lọ wo idije AFCON ni Egypt.

''Bawo ni Gomina ṣe fẹ na aduru owo yẹn nigba to ṣe wi pe ọmọ igbimọ lasan ti aarẹ gbe dide lọ si Egypt ni?''

O tẹsiwaju pe Sanwo Olu kan kọwọrin pẹlu igbimọ naa lọ si Egypt ni gẹgẹ bi ''ẹgbẹ alatẹwọ''

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCAN: Samson ni ọrọ awọn ajinigbe ti gba àpérò ní Naijiria