Ṣíṣe-ṣíṣe bá Arsenal,Wolves dá bàǹtẹ́ ìyà fún wọn

aworan Agbabọọlu Arsenal

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aṣọ ti bọ lara ọmọyẹ, Arsenal rin hoho wọ ọja pẹlu bi wọn ti ṣe fidirẹmi goolu mẹta si ookan lọwọ Wolves.

Eyi ni igba keji ti Arsenal fi iya panu lọwọ awọn ẹgbẹ agbabọọlu miran ninu idije Premiership laarin ọsẹ kan.

Lọjọ ajinde to kọja ni Crystal Palace fagba han Arsenal pẹlu ami ayo 3-2 ni Emirate.

Esi yi jẹ ohun to mu irẹwẹsi ọkan ba pupọ alatilẹyin ẹgbẹ naa.

Bi ere bi ere ni ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Wolves bẹrẹ amọ nigba ti wọn yoo fi de ipari abala kini,Arsenal ti lọ mu bọọlu ninu awọn nigba ẹmẹta.

Neves Doherty ati Jota lo jẹ goolu mẹta naa.

Abala keji ko yatọ si ikini ti Wolves ko si dawọ kikan ilẹkun Arsenal duro.

aworan akọnimọgba Arsenal

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Amọ ni igba ti o di iṣẹju ọgọrin, Papastathopoulos da goolu kan pada fun Arsenal.

Gbogbo apa ti Arsenal ṣa,pabo lo jasi ti ifẹsẹwọnsẹ naa si pari ni ayo mẹta si ọkan.