Ole wọ gàu! Man U tún ṣubú dàánù bí City ti dìgbájú rù wọ́n

aworan awọn agbabọ́ọlu Man City

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Manchester City ti da ori Liverpool kọja lati bọ si ipo ikini lori afara liigi Premiership pẹlu bi wọn pegede lori Man Utd pẹlu goolu meji si ọkan.

Ifẹsẹwọnsẹ naa ti o mu iriwisi orisirisi wa gbona janjan lati ibẹrẹ titi di ipari.

Ni bayi, Manchester City ti n fi ami ayo kan sagba Liverpool ti o ni ami ayo méjídínláàdọ́rùn ún ti Manchester City si ni mọ́kàndínláàdọ́rùn ún.

Bernado Silva ati Leroy Sane ni wọn jẹ goolu mejeeji ti wọn fi pegede ninu ifẹsẹwọnsẹ naa

Ikọ Ole Gunnar Solkjaer ko ribi kuro ni ipo kẹfa ti wọn wa lori afara liigi lati ọjọ yi.