Premier League: Arsenal àti Man U dèrò Europa League

Agbabọọlu Arsenal ati Manchester United Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Idije Premier League

Aṣe tẹni to de laari, a ko mọ tẹni to n bọ. Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal naa ti tẹle Manchester United lọ si idije Europa.

Arsenal naa ta ọmi ayo kọọkan pẹlu ikọ agbabọọlu Brighton ni papa iṣere Emirates, eleyi to tumọ si pe wọn ko le de ipo kẹrin mọ lori tabili idije Premier League fun saa yii.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Idije Premier League

Ẹlẹsẹ ayo Pierre-Emerick Aubameyang lo kọkọ gba pẹnariti sawọn fun Arsenal lẹyin iṣẹju mẹsan an ti ere bọọlu naa bẹrẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'500 level'' ni mo wà nígbà tí mo di adélé Ọba'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionHelen Paul sọ idi tó fi gba orúkọ ní kékere

Ṣugbọn Glenn Murray dayo ọhun pada lẹyin to yẹ ile Arsenal pẹlu pẹnariti ti wọn fun ẹgbẹ agbabọọlu Brighton.

Ẹwẹ, ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti dero Europa League bayiilẹyin ti wọn ta ọmi alayo kọọkan pẹlu Huddersfield Town.

Esi ifẹsẹwọnsẹ yii ti ṣakoba fun ikọ Man U lati kopa ninu idije Champions League ni saa to n bọ.

Scott McTominay lo kọkọ gba goolu sawọn fun Manchester United lẹyin iṣẹju mẹjọ ti wọn bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ naa.

Ṣugbọn Isaac Mbenza dayo naa pada lẹyin iṣẹju mẹẹdogun ti abala keji ere bọọlu ọhun bẹrẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Man U dero Europa

Ẹgbẹ agbabọọlu Man U kuna bayii lati yege fun idije Champions League ni saa ere bọọlu to n bọ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Man U dero Europa

Chelsea ati Tottenham ti wẹ tan kan-in kan-in bayii lati ṣoju ilẹ Gẹẹsi ninu idije Champions League ni saa to n bọ.