Premier League: Nàn sẹ́ni ọ́ gọ̀ ni Chelsea fi ṣe fún Watford

Awọn agbabọọlu Chelsea Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Chelsea fakọyọ

O fẹ dabi ẹni pe Chelsea ni ipo lati dije fun UEFA Champions League ni saa to n bọ yoo ja mọ lọwọ laarin awọn wọn ati Arsenal ati Manchester United.

Alubami ni Chelsea lu ẹgbẹ agbabọọlu Watford lọjọ Aiku eleyi to fun wọn lanfaani lati wa nipo kẹta bayii lori tabili Premier League.

Ruben Loftus-Cheek, David Luiz ati Gonzalo Higuain lo gba goolu sawọn fun Chelsea ti wọn si jawe olubori pẹlu ami ayo mẹta sodo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'500 level'' ni mo wà nígbà tí mo di adélé Ọba'

O ku ifẹsẹwọnsẹ kan ṣoṣo lo ku fun Chelsea bayii lati gba a ti msaa bọọlu yii yoo fi pari.

Ikọ Chelsea ti wa ni ipele to kangun si aṣekagba ninu idije Europa bayii ninu eyi ti wọn ta ọmi pẹlu ikọ Frankfurt lati orilẹede Germany.

Related Topics