Ramadan Fast: wo àwọn orílẹ̀èdè tí wákàtí ààwẹ̀ wọn gùn ju ti Nàìjíríà lọ àti àwọn èèwọ̀ oúnjẹ lásìkò ààwẹ̀

Ounjẹ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ounjẹ
Àkókò:
Oòrùn ràn: :Oòrùn ràn
Oòrùn wọ̀: :Oòrùn wọ̀
Àkókò:
Oòrùn ràn: :Oòrùn ràn
Oòrùn wọ̀: :Oòrùn wọ̀
Àkókò:
Oòrùn ràn: :Oòrùn ràn
Oòrùn wọ̀: :Oòrùn wọ̀
 • Afghanistan
  Àkókò: 15hrs 31mins
  Oòrùn ràn: 04:45
  Oòrùn wọ̀: 18:55
 • Australia
  Àkókò: 11hrs 25mins
  Oòrùn ràn: 06:46
  Oòrùn wọ̀: 16:58
 • Brazil
  Àkókò: 11hrs 57mins
  Oòrùn ràn: 06:37
  Oòrùn wọ̀: 17:29
 • Canada
  Àkókò: 17hrs 2mins
  Oòrùn ràn: 05:15
  Oòrùn wọ̀: 20:28
 • Chile
  Àkókò: 11hrs 25mins
  Oòrùn ràn: 07:33
  Oòrùn wọ̀: 17:46
 • China
  Àkókò: 16hrs 11mins
  Oòrùn ràn: 04:51
  Oòrùn wọ̀: 19:30
 • Egypt
  Àkókò: 15hrs 5mins
  Oòrùn ràn: 04:57
  Oòrùn wọ̀: 18:47
 • France
  Àkókò: 17hrs 44mins
  Oòrùn ràn: 05:59
  Oòrùn wọ̀: 21:37
 • Greenland
  Àkókò: 20hrs 48mins
  Oòrùn ràn: 03:44
  Oòrùn wọ̀: 23:06
 • Iceland
  Àkókò: 20hrs 47mins
  Oòrùn ràn: 03:46
  Oòrùn wọ̀: 23:06
 • India
  Àkókò: 14hrs 58mins
  Oòrùn ràn: 05:26
  Oòrùn wọ̀: 19:10
 • Indonesia
  Àkókò: 12hrs 50mins
  Oòrùn ràn: 05:55
  Oòrùn wọ̀: 17:44
 • Kenya
  Àkókò: 13hrs 17mins
  Oòrùn ràn: 06:27
  Oòrùn wọ̀: 18:32
 • Libya
  Àkókò: 15hrs 48mins
  Oòrùn ràn: 06:03
  Oòrùn wọ̀: 20:05
 • Morocco
  Àkókò: 15hrs 28mins
  Oòrùn ràn: 05:21
  Oòrùn wọ̀: 19:28
 • Nigeria
  Àkókò: 13hrs 29mins
  Oòrùn ràn: 06:30
  Oòrùn wọ̀: 18:57
 • Russia
  Àkókò: 18hrs 35mins
  Oòrùn ràn: 04:04
  Oòrùn wọ̀: 20:50
 • Saudi Arabia
  Àkókò: 14hrs 38mins
  Oòrùn ràn: 05:06
  Oòrùn wọ̀: 18:34
 • Senegal
  Àkókò: 14hrs 12mins
  Oòrùn ràn: 06:40
  Oòrùn wọ̀: 19:34
 • South Africa
  Àkókò: 11hrs 50mins
  Oòrùn ràn: 06:43
  Oòrùn wọ̀: 17:26
 • Tanzania
  Àkókò: 13hrs 3mins
  Oòrùn ràn: 06:39
  Oòrùn wọ̀: 18:29
 • UK
  Àkókò: 18hrs 1mins
  Oòrùn ràn: 04:57
  Oòrùn wọ̀: 20:58
 • USA
  Àkókò: 15hrs 29mins
  Oòrùn ràn: 05:46
  Oòrùn wọ̀: 19:54

Kókó ọ̀rọ̀: Wíwo àkókò dá lórí olú ìlú orílẹ̀èdè kọ̀ọ̀kan

Orísun: aladhan.com ati islamicfinder

Ramadan ti bẹrẹ ni pẹrẹu, bi ààwẹ̀ gbigba ṣe pọn dandan bẹẹ naa ni awọn ounjẹ ti ẹnikẹni to ba n gbawẹ nilo akiyesi.

Onimọ̀ nipa ounjẹ jijẹ, Oyedeji oluwatobi jẹ ko di mimọ wi pe nigbakuugba ti eeyan ba n gba awẹ, awọn irinṣẹ ara yoo ti paju de to ba maa fi to akoko iṣinu.

Oluwatobi ni ko boju mu lati maa lo ohun to lee pa ara lati fi ṣinu dipo awọn eroja to lee bẹrẹ si ni ṣi awọn irinṣẹ ara naa pada eyi to ti pa oju de.

" A ni lati fun un ni nkan ti yoo maa jẹ ko ṣi diẹ diẹ to jẹ wi pe a tun ṣe awọn eroja ara lokun pada titi ara yoo ṣe le gba awọn". O ni kii ṣe bi awọn okele nla nla ti a da bii okuta".

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionRAMADAN: Onímọ̀ ẹ̀sin sọ nípa isẹ́ láádá àti làádà

Nkan bii ounjẹ to lomi dara lati kọkọ fi ṣinu lati le pese inu silẹ fun ounjẹ miiran. Lẹ́yìn eleyii gan, o ṣi yẹ ki wọn mu nkan bii miliiki ki wọn to wa jẹ iru ounjẹ ti wọn maa n jẹ tẹlẹ.

To ba ṣe eso, yoo jẹ ki ounjẹ wu eniyan jẹ kìí ṣe ti ka sare kọ ounjẹgelete siwaju ki a wa pa taarọ, ọsan ati talẹ pọ lẹẹkan.

Onimọ nipa ounjẹ tun tẹnu mọọ pe kii ṣe awn eso ti wn ti da kẹmika pọ mọ lo yẹ bi ko ṣe eyi to ṣẹ wa lati oko.

Fun awọn to ni aisan ọgb inu, Oluwatobi ni awọn eso to ni oro ninu ko dara fun wọn lati fi ṣinu tori naa, o yẹ ki wọn ri onimọ nipa ounjẹ ti yoo ya atẹ ounjẹ fun wọn ki wọn to maa yan ounjẹ ti wọn yoo fi ṣinu ati iye akoko to yẹ ki wọn fi gbawẹ.

Ma ṣe jẹ

Onimọ nipa ounjẹ Oluwatobi kilọ pe ki ẹni to ba n gbawẹ ṣọra fun ounjẹ lile gẹgẹ bi ohun akọkọ lati fi ṣinu aawẹ.

Bakan naa, o ṣe apẹrẹ awọn nkan dindin gẹgẹ bi ohun ti ko yẹ keeyan kọkọ fi ṣinu.

Ohun ti o le jẹ

 • Eso olomi
 • Ogi agbado
 • Ewebẹ
 • Anọmọ
 • Iṣu to rọ ati bẹẹ bẹẹ lọ ṣaaju ounjẹ to le.