Champions League: Ṣé Liverpool ò wọ gàu lọ́wọ́ Messi báyìí?

Salah, Messi ati Firmino Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Idije Champions League

Ayo mẹta sodo ni Liverpool jẹ lọwọ Barcelona ni papa iṣere Camp Nou ninu abala akọkọ ifẹsẹwọnsẹ to kangun si aṣkagba idije UEFA Champions League.

Lalẹ oni ni ipele keji ifẹsẹwọnsẹ naa yoo waye ni papa isere Anfield nilẹ Gẹẹsi.

Ṣugbọn ibeere kan ti ọpọ ololufẹ ere bọọlu n beere lori ayelujara ni pe ta gan an ni yoo gba ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool lọwọ elege-ara Lionel Messi.

Ẹwẹ, akọnimọọgba ikọ Liverpool, Jurgen Klopp ti sọ pe ẹru ko ba odo ẹgbẹ agbabọọlu naa bo tilẹ je pe awọn ẹlẹsẹ ayo meji Mohamed Salah ati Roberto Firmino ko ni le kopa ninu ere bọọlu ọhun lẹyin ti wọn farapa.

Klopp ni ikọ Liverpool ṣetan lati rii wi pe ẹgbẹ agbabọọlu tun pegede fun aṣekagba idije Champions League lẹẹkan sii.

Luis Suarez to darapọ mọ Barcelona lati Liverpool ni ikọ Barca gbọdọ ṣọra ni papa iṣere ki wọn maa ba yọ ṣubu.

Suarez ni Liverpool kii ṣe ẹran rirọ nigba kugba ti wọn ba n koju ẹgbẹ agbabọọlu miran ni papa isẹre Anfield

Suarez gba goolu kan sawọn nigba ti Messi jẹ goolu meji ninu abala akọkọ ifẹsẹwọnsẹ yii to waye ni Camp Nou.