#LIVBAR:Oróò! Liverpool ṣé Barcelona ríṣarìṣa pẹ̀lú àtòrì ẹlẹ́nu mẹ́rin

Lionel Messi Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Messi dori kodo

Ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool ti jajabọ tẹsiwaju lati kopa ninu aṣekagba idije Champions League pẹlu bi wọn ṣe doju Barcelona bole ni Anfield.

Goolu mẹta ni Barcelona fi n lewaju lati abala kini ifẹsẹwọnsẹ wọn lọsẹ to kọja amọ Liverpool da goolu na pada ti wọn si tẹsiwaju lati bori Barcelona pẹlu ami ayo mẹrin si mẹta.

Divock Origi lo kọkọ jẹ goolu ni iṣẹju keje ifẹsẹwọnsẹ naa ti o si fi goolu mi da Barcelona loro ni iṣẹju kọkandinlogọrin ti o fi jẹ goolu mẹrin si odo.

Bi ala ni ọrọ naa ri loju ọpọ alatilẹyin ẹgbẹ Liverpool nitori pe awọn to jẹ eekan ẹgbẹ wọn meji Mohammed Salah ati Firminho ko kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.

Image copyright Getty Images

Amọ aisini ori papa wọn ko fi Liverpool rara.

Ninu idije Champions League,iru itu bayi sọwọn ti awọn eeyan si n kan sara si Liverpool.

Tottenham ati Ajax ni yoo koju ninu ifẹsẹwọnsẹ keji lati mọ ẹni ti yoo pade Liverpool ninu aṣekagba idije naa ti yoo waye ni Madrid.

Awọn iroyin mii ti ẹ le nifẹ si

Duro Ladipọ, ìlúmọ̀ọ́ká òṣèré tíátà àti ọmọ àlúfà tí kò gbàgbé àṣà ìbílẹ̀

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'500 level'' ni mo wà nígbà tí mo di adélé Ọba'