Amaju Pinnick: Ìjọba Naijiria bèrè bó ṣe ná $8,400, N4bn

Amaju Pinnick Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Ààrẹ erébọ́ọ̀lù Naijiria, Amaju Pinnick ti bu ẹnu àtẹ́ lu ẹ̀sùn wí pé òun se màgòmágó pẹ̀lú owó NFF.

Aarẹ ẹgbẹ agbabọọlu lorilẹede Naijiria, Amaju Pinnick ati awọn mẹrin miiran ti fi oju ba ile ẹjọ lori ẹsun pe wọn lu owo to to ẹgbaarin o le ni irinwo owo dọla ilẹ okeere ti Ajọ erebọọlu ni Agbaye, FIFA san fun Ajọ erebọọlu Naijiria(NFF).

Ẹsun ti wọn fi kan an ni wi pe owo ilẹ okeere naa ni Ajọ FIFA san fun orilẹede Naijiria fun afarahan ninu idije ife agbaye ti Brazil lọdun 2014.

Awọn marun ti wọn fẹsun kan naa ni wọn ni wọn tun gbe miliọnu mẹrin Naira owo ajọ naa lai gba asẹ lati gbe owo naa kuro ni apo ijọba lọ si ibomiran.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Owó tí mo ń rí lórí Garri ni mo fi ń ran ọkọ lọ́wọ́'

Amọ ni ọpọ igba ni Amaju Pinnick ti sọ wi pe ẹẹbu ni ẹsun lilu owo ilu ni ponpo ti wọn fi kan oun.