Lucas Moura: Ọmọ atàpátadìde tó gbé Tottenham wọ àsekágbá ìdíje Champions League

Lucas Moura Image copyright BBC Sport

Bi eeyan ba ma n ta tẹtẹ lori bọọlu ,nkan to n ṣẹlẹ ninu idije Champions League ọdun yi le mu ki eyan padanu owo tabi ki o di olowo tabua.

Ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ to ti waye ni abala to kangun si aṣekagba idije naa,awọn agbabọọlu kan ti pitu ti wọn si yii oju esi ifẹsẹwọnsẹ pada bi ẹni pidan.

Ninu wọn la ti ri Gini Wijnadum ati Divock Origi ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool ti wọn jẹ goolu meji meji ninu mẹrin ti Liverpool fi sagba Barcelona.

Amọ eleyi ti o fa iriwisi lọdọ awọn alatilẹyin ere boolu ni ti Lucas Moura ẹgbẹ Tottenham to jẹ goolu mẹta ni abala keji ifẹsẹwọnṣẹ Tottenham ati Ajax.

Ta ni Loucas Moura

Ọmọ orileede Brazil ni Loucas Moura ti o si wa si Tottenham lati ẹgbẹ PSG to ta a ni ọdun 2018 niye owo miliọnu mẹtalelogun poun.

Unai Emery to jẹ akọnimọọgba Arsenal lọwọ bayii ni o ta Moura fun Tottenham.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Unai Emery akọnimọọgba Arsenal pẹlu Lucas Moura nigba ti o wa ni PSG

Oun tawọn kan sọ nipa iṣẹlẹ yii ni pe wọn ta Moura ki wọn ba le faye silẹ fun Neymar ti wọn n gbe bọwa lati Barcelona.

Igbagbọ nigba naa ni pe Neymar yoo le mu ki PSG gba ife eye Champions League amọ loni yii, Moura ti wọn ta lọ si Tottenham lo pa iru itu yii.

Awọn alatilẹyin Tottenham ko gbagbe ọrọ yi wọn si ti bẹrẹ si ni fi naka abuku si Unai Emery ti o n dari ẹgbẹ alatako wọn Arsenal.

Ọmọ Atapatadide ni Moura

Lati kekere ni Lucas Moura ti bẹrẹ si ni gba bọọlu ni ilu Sao Paulo lorilẹede Brazil.

Agbegbe ibi to dagba si jẹ ibi ti awọn ti ko lowo pupọ n gbe, amọ pẹlu gbogbo ipenija to yi ka,Moura di ilumọka agbabọọlu.

Loju opo Twitter, eeyan kán kan sara si Moura bi o ti ṣe fakọyọ laaarin awọn akẹgbẹ rẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Ajax.

Yatọ si ifẹsẹwọnsẹ Totteham ati Ajax, Loucas Moura ti fakọyọ ninu ifẹsẹwọnsẹ miran to ti jẹ awọn goolu to ṣokunfa itẹsiwaju ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham ninu awọn idije ti wọn ti kopa ninu rẹ.

Lara wọn la ti ri goolu rẹ to jẹ ni ile Barcelona ninu idije komẹsẹoyo Champions league lọdun yii, to mu ki Tottenham tẹsiwaju lọ abala to kan.

Bakanna lo jẹ goolu meji lọjọ Kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹjọ nigba ti Tottenham koju Manchester United ti wọn si pegede pẹlu goolu 3-0.

Bi a ko ba gbagbe, akọkọ goolu mẹta ti Loucas Moura jẹ ni Yuroopu waye ni Ọjọ Kẹtala, Oṣu Kẹrin, ọdun 2019 ninu ipade Tottenham ati Huddersfield.

Related Topics